ỌWỌ TẸ AJAGUNGBALẸ MẸFA L'ẸNUGU, ILE ONILE NI WỌN LỌỌ WO DANU - IROYIN AWIKONKO

YÀJÓ-YÀJÓ
Wednesday, June 19, 2019

ỌWỌ TẸ AJAGUNGBALẸ MẸFA L'ẸNUGU, ILE ONILE NI WỌN LỌỌ WO DANU

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, ko daju pe awọn gendekunrin mẹrin kan ti wọn ni wọn ko niṣẹ meji ju iṣẹ ajagungbalẹ lọ yoo bọ ninu wahala ti wọn ko ara wọn si latari bi wọn ṣe sọ pe wọn lọọ digun wo ile kan ti wọn n kọ lọwọ.

Awọn mẹfa naa ni: Ikechukwu Nomẹh, Tochukwu Nnamani, Uchenna James, Victọr Asigah, Agustin Tochukwu ati Anthony Nwobodo. A gbọ pe ile kan tawọn agbaṣẹṣe n kọ lọwọ lagbegbe Emene-Nike nipinlẹ Ẹnugu ni wọn ko ibọn atawọn nnkan ija oloro lọọ wo danu, ti wọn si tun lu awọn oṣiṣẹ naa nilukulu.

A gbọ pe awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni wọn ranṣẹ sawọn ọlọpaa, ti wọn si ran awọn oṣiṣẹ ọga ọlọpaa orilẹ-ede yii, (Operatives of the Inspector-General of Police Special Intelligence Responses Team (IRT)) lati da si wahala naa.

Wọn loo ti pẹ tawọn ọdaran ti ẹ n wo oju wọn yi ti wa nidi iṣẹ naa, ati pe awọn gan an ni wọn n da alaafia ilu naa mu loore-koore, ti wọn ko si fawọn eeyan lọkan-balẹ.

Bẹẹ la tun gbọ pe awọn ọlọpaa ti n wa wọn tipẹ, ko too di pe aṣiri wọn tu yii, ati pe obinrin kan ti wọn pe ni Ngozi Egbe ni wọn fẹẹ fipa gba dukia lọwọ, ti wọn si tun wo ẹgbẹ kan lara ile obinrin naa to n kọ lọwọ.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI