IPO TAWỌN ALAINI WA LORILẸ-EDE YI KII JẸ KI N LE SUN LORU - ỌṢINBAJO - IROYIN AWIKONKO

YÀJÓ-YÀJÓ
Wednesday, June 19, 2019

IPO TAWỌN ALAINI WA LORILẸ-EDE YI KII JẸ KI N LE SUN LORU - ỌṢINBAJO

Gbenga Ọladipupọ

Igbakeji Aarẹ orilẹ-ede yi, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ti sọ pe ipo tawọn alaini wa lorilẹ-ede yi ko tẹ oun lọrun rara, to si ni ojoojumọ ni kii jẹ koun maa ri oorun sun loore-koore.

Ọjọgbọn Ọṣinbajo tun sọ pe ṣe lo maa n kan oun lominu pupọ, to si jẹ pe ko si ironu meji toun n ro lasiko yi bi ko ṣe ọrọ awọn alaini naa lọ, tori pe awọn gan an lo pọ ju ti wọn dibo foun ati Aarẹ.

Aṣalẹ ounjẹ ati ifọrọwerọ kan to waye niluu Eko lalẹ ana Tuside, eyi to ṣe pẹluu awọn awọn ọmọ ẹgbẹ kan ni Harvard Business School ni igbakeji Aarẹ ti sọrọ naa jade.

O ni awọn ileri tijọba ṣe fun wọn ni lati mu ayipada rere de ba igbesi aye wọn, to si ti n foju han bayii pe laarin asiko perete si asiko yi, wọn yoo bẹrẹ sii rẹrin ayọ nitori ipe igba rere yoo pada bọ sipo fun wọn.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI