NITORI OWO OṢU, AWỌN OLUKỌ FẸHONU HAN L'ONDO, WỌN DA IṢẸ SILẸ LOJIJI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, June 19, 2019

NITORI OWO OṢU, AWỌN OLUKỌ FẸHONU HAN L'ONDO, WỌN DA IṢẸ SILẸ LOJIJI

Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun
 
Ko tii sẹni to le sọ ibi ti ọrọ naa yoo ja si titi dasiko ta a kọ iroyin yi tan latari bawọn oṣiṣẹ atawọn olukọ ile ẹkọ gbogboniṣe ti Rufus Giwa to wa niluu Ọwọ, ipinlẹ Ondo ṣe da iṣẹ silẹ lojiji lẹyin ifẹhonu han lori owo oṣu marun un wọn ti wọn ko tii ri gba.

Ana Tuside la gbọ pe awọn eeyan naa ṣe ifẹhonu han alaafia lasiko to ku iṣẹju diẹ ki wọn bẹrẹ idanwo lọgba ile-ẹkọ naa. Se la gbọ pe wọn ti gbogbo ilẹkun to wọnu ọgba ile ẹkọ naa pa, pe ẹnikẹni ko nii wọle, ayafi bawọn ba gba owo oṣu wọn.
 
Nigba to n sọrọ alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ poli (ASUP) nile ẹkọ naa, Ọgbẹni Rafiu Ijawoye fẹsun kan awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa pe wọn ko bikiti fun alaafia awọn oṣiṣẹ, ti wọn ko si ṣetan lati dawọn lohun pẹluu oju aanu.

O ni kaka ki awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa san awọn owo ajẹẹlẹ awọn oṣiṣẹ lẹyin ti ijọba ipinlẹ naa ti gbe owo oni biliọnu meji din diẹ (N1.7b) silẹ fun wọn lati fi san awọn gbese ti wọn jẹ, bẹẹ si ni wọn ko ṣe eto igbega fawọn lati ọdun 2017.

Ijawoye wa a rawọ ẹbẹ si Gomina ipinlẹ naa, Rotimi Akeredolu pe ko tete wa a yan olori min in fawọn ni ile ẹkọ gbogboniṣe naa, ati pe ẹni ti yoo mu idagbasoke ba ile ẹkọ naa ni ko yan.

Loju ẹsẹ ni ni agbaniwọle fidihẹ (Acting Registrar) nile ẹkọ naa gbe atẹjade sita pe kawọn akẹkọọ patapata ko gbogbo ẹru wọn kuro nile ẹkọ naa digba ti wọn yoo pe wọn pada, iyẹn lẹyin ti wọn ba yanju wahala naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI