KAYEEFI NLA: IJI WO AAFIN KABIYESI OLOWU L'ỌṢUN, BẸẸ LO TUN BA MỌTO OLOWO NLA JẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 1, 2019

KAYEEFI NLA: IJI WO AAFIN KABIYESI OLOWU L'ỌṢUN, BẸẸ LO TUN BA MỌTO OLOWO NLA JẸ

rainstorm destroys palace Osun community
Ko din ni ọgbọn ile ti iji ojo ti wo lulẹ lọjọ Tọside to kọja yi, to si tun wo ile Kabiyesi, Ọba Adekunle Makama Oyelude tii ṣe Olowu tiluu Kuta nijọba ibilẹ Ayedire, ipinlẹ ọṣun.

Fun bii wakati meji gbako la gbo pe ojo nla naa fi rọ niluu Kuta, to si tun fẹ atẹgun nla, to si pe awọn eeyan bẹrẹ sii sare kijo-kijo.

Bi iji ṣe n ka orule ile, bẹẹ lo n ya awọn ogiri ile lulẹ, to si mu kawọn eeyan bẹrẹ sii farapa.

AWIKONKO gbọ pe ko din ni miliọnu marun un lawọn dukia to ṣofo danu ninu iji naa, to si tun ba ọkan lara awọn mọto Kabiyesi naa jẹ.

Ilu Abuja la gbọ pe Kabiyesi, Ọba Oyelude wa lasiko tiṣẹlẹ naa waye, to si jẹ pe latigba naa lawọn eeyan ti n ba Kabiyesi naa kẹdun ijamba yi.

Oluwo tiluu Iwo, Ọba Abdul-Raṣheed Adewale Akanbi naa de Aafin yi lati wo nnkan to ṣẹlẹ, to si bawọn kẹdun pẹluu, to si tun ke gbajare sijọba lati da si iṣẹlẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI