MI O LE GBAGBE ỌJỌ TI FAITHIA BALOGUN SỌRỌ BURUKU SI MI - MISITA MẸRRY - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉTuesday, June 11, 2019

MI O LE GBAGBE ỌJỌ TI FAITHIA BALOGUN SỌRỌ BURUKU SI MI - MISITA MẸRRY


Bi wọn ba n sọ nipa awọn irawọ oludari-ere to n gbe aṣa, iṣe ati ede Yoruba ga kaakiri ilẹ Adulawọ, odu ni Ọmọba Adekọla Adeniji Ọjẹlere, ki i ṣaimọ f'oloko, paapaa lagbo oṣere lorileede Naijiria.


Ko lo n ka lawọn sinima ti Adekọla Ọjẹlere tọpọ awọn eeyan mọ si Misita Mẹrry ti kopa, yala nipa akọwe iranti, ayaworan, oṣere tabi oludari-ere. Oriṣiriṣi aami ẹyẹ lo ti gba lori ipa to ti ko nidi iṣe tiata.

Laipẹ yi ni Misita Mẹrry to fi orilẹ-ede Ghana ati Naijiria ṣe'bugbe b'AWIKONKO sọrọ, paapaa nipa awọn adojukọ ẹ lasiko to ṣẹṣẹ n dide bọ nidi iṣẹ naa, to si ni ọjọ kan toun ko le gbagbe lọjọ ti ọkan lara awọn agba oṣere-binrin nni, Faithia Balogun sọrọ buruku soun bi ẹni ti ko le ni laari mọ laye. Ẹkunrẹrẹ nnkan to ba wa sọ re e: Ẹ ku igbadun

ORUKỌ MI
Adekọla Ọjẹlere lorukọ mi, Misita Mẹrry lọpọ awọn eeyan mọ mi si, mo jẹ ọmọ bibi ilu Ipapo nipinlẹ Ọyọ. Olukọ-itan, oludari-ere, elere ori itage olootu sinima, ni mi, bẹẹ ni mo tun jẹ akọwe iranti.

BI MO ṢE BẸRẸ
Ọdun 2008 ni mo bẹrẹ iṣẹ tiata lọdọ ọga mi, Azeez Adelakun, ẹni to pada fa mi le ọga mi, Oscar Bọsun Adesanya lọwọ lati kọ mi niṣẹ akọwe iranti, asiko yẹn, inu ẹgbẹ oṣere ANTP la wa nigba yẹn ni ti ẹkun Ikẹja. Ajala Jalingo ni gomina wa nigba naa. Nigba ti mo maa bẹrẹ, awọn obi mi ko fara mọn ọn pe ki n lọ darapọ awọn elere ori itage, ṣugbọn ọkọ ẹgbọn mi kan to ti di oloogbe bayii, Pasitọ Abiọla Fọlarin lo ba iya mi sọrọ ti wọn fi gba mi laaye, bo tilẹ jẹ pe ko dun mọ wọn ninu. Funra mi ni mo lọ fi ara mi sẹnu ẹkọṣẹ, ṣugbọn mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ni bayii, inu awọn naa ti n dun pe mo ti n ṣe aṣeyọri, wọn si ti n fi mi yangan. Ni bayii, mi o ṣe akọwe iranti mọ tipẹ, oludari-ere ni mo n ṣe bayii.

AWỌN TI A JỌ BẸRẸ
Wọn pọ ti mi o le darukọ tan, ṣugbọn maa darukọ diẹ lara wọn. Afunṣọ Kazeem ati Adisa Yusuf tawọn eeyan tun n pe ni Climax, awọn mejeeji ni wọn jẹ gbajugbaja ayaworan bayii. Okiki Afọlayan, toun jẹ akọwe iranti lọdun naa lọhun ṣugbọn to ti di gbajumọ oludari sinima bayii, Victoria Kọlawọle, Tọpẹ Ọṣọba, Abọlanle Abdulsalam atawọn min in bẹẹ bẹẹ lọ.

LARA AWỌN SINIMA TI MO TI KOPA
Mi o le ranti tan, ṣugbọn sinima akọkọ ti mo kọkọ kopa ninu ẹ ni ‘Ko Si Oṣuwọn’, Toyin Aiṣida lorukọ olootu itan naa bo tilẹ jẹ pe o ti di oloogbe bayii, Oscar Adesanya ni akọwe iranti sinima naa, Ọmọba Jide Kosọkọ lo dari ẹ nigba naa. Mo ti ṣe akọwe iranti sinima to pọ, diẹ lara wọn ni ‘Kọnyinsọla Oni Nnkan Ọkunrin’, ‘Sisi Pẹlẹbẹ’, ‘Kikẹlọmọ Oluṣọ’, ‘Ọgbọn Imọ ati Oye’ atawọn min in. Mo tun ti dari ọpọlọpọ sinima ti mi o le ka rara, diẹ lara wọn ni ‘Ẹwa Ibale’, ‘Ikọsẹ’, ‘Eesu’, ‘Igi Ẹsan’, ‘Perosọkọ’, ‘Out of Love’ to jẹ sinima ọlọsẹ-ọsẹ ti wọn ṣafihan ẹ lori tẹlifiṣan AIT atawọn min in bẹẹ.

DIẸ LARA AWỌN IPENIJA MI
Loootọ, ko si iṣẹ ti ko ni ipenija ninu, nigba ti mo n kọ iṣẹ, lara awọn ipenija ti mo dojukọ ni owo lati maa fi wọ mọto lọ si oko ere kaakiri. Ibeere yi mu mi ranti ọjọ kan, ti mo si fẹẹ dupẹ lọwọ ọga mi, Oscar Bọsun Adesanya tori pe ko mu mi gẹgẹ bi ọmọṣẹ, ṣe lo mu mi gẹgẹ bi aburo ẹ, ti a ba lọ ṣiṣẹ, o maa fun mi lowo ati ounjẹ. Ibeere yi lo mu mi ranti ọjọ kan, igba yẹn, ibi kan ti a n pe ni Act Council to wa ni Ikẹja la ti maa n ṣe ipade ni gbogbo Ọjọbọ Tọside akọkọ ninu oṣu. Ọjọ kan ni mo fẹsẹ rin lati Ijaye titi de Ikẹja lọ si ipade yi, bi ọga mi ṣe gbọ lo ti bẹrẹ sii fun mi lowo mọto. Ipenija pọ, amọ ṣa, ẹni to ba mọ nnkan to n ṣe ati nnkan to n le oun, ko ni i wo ipenija yẹn. Mo sọ fun un yin pe awọn obi mi ko fara mọ ọn pe ki n ṣe tiata, idi ẹ lo fi jẹ pe ninu ki wọn fun mi lowo diẹ, tabi ki wọn ma fun mi rara. Ati pe nigba ti mo ṣẹṣẹ n da duro, ti mo nṣe akọwe iranti, ti a ba lọ si oko ere, olootu le sọ pe ka fi nọmba banki wa silẹ, tabi pe ka gba iwe sọwe-dowo (cheque), ti a ba si de banki, owo le ma si ninu apo owo wọn. Sibẹ, mo dupẹ lọwọ Ọlọrun lonii tori pe nnkan n ri bi a ṣe n gbadura.

NIPA T’AWỌN AKUKỌ GAGARA NIDI IṢẸ TIATA
Ki i ṣe pe idi iṣẹ yi nikan ni akukọ gagara wa, gbogbo ibiṣẹ ni, ki i si i ṣe pe gbogbo awọn akukọ gaga ni wọn ko fẹ ki kekere kọ, ṣugbọn awọn akukọ gagara kan wa ti wọn n wo o pe bi kekere ba kọ, awọn ko ni i kọ mọ, ti ko si ri bẹẹ. Awọn kan si gba pe bi akukọ kekere ati akukọ nla ba kọ, ẹkọ ni yoo jẹ fawọn eeyan. Bi apẹẹrẹ, ọga mi Oscar Adesanya, titi di ọla, aṣeyọri mi lo maa n wa, mo ranti igba ti mo fẹẹ ṣe sinima mi ẹlẹẹkeji, o tun fun mi lowo kun owo ọwọ mi, ati pe bo tilẹ jẹ pe wọn ko raaye wa, iṣẹju-iṣẹju ni wọn n pe mi lati beere bo ṣe n lọ. Awọn kan ti sọ fun mi ri pe awọn fẹẹ wo ibi ti mo fẹ gbe e gba lati ga nidi iṣẹ, ti mo si dupẹ pe Ọlọrun gbe ogo ẹ dide fun mi. Mo ti lawọn ọmọ ti mo ti gbe dide nidi iṣẹ yi, lara wọn ni Adekunle Azeez ti inu mi si n dun sii.

ASIKO TI MO KABAMỌ JU NIDI IṢẸ TIATA
Ọjọ kan ṣoṣo ti mi o le gbagbe nigbesi aye mi ni igba ti a n ya sinima Ọgbọn lọwọ, emi ni mo ṣe akọwe iranti sinima naa, ọrọ si ṣebi ọrọ laarin emi ati Faithia Williams, to si jẹ pe amugbalẹgbẹ (P.A) ẹ lo ṣe aṣiṣe naa, ṣugbọn ti Faithia funra ẹ ti ran an niṣẹ. O ṣa a faraya pupọ lọjọ naa to jẹ pe o ko ibanujẹ si mi lọkan, paapaa nigba to tun sọ pe ko si lokeṣan toun ba ti pade mi, oun maa le mi danu ni. O sọrọ gan an bi i pe mi o jẹ eeyan rara. Ọpẹlọpẹ ọga wa, Dede Mati to dari sinima yi lọjọ naa lọhun pe mi o ṣe nkankan.

IGBA TI INU MI DUN JU
Mi o le gbagbe ọjọ ti mo kọkọ gba awọọdu akọwe iranti to darajulọ lọdun 2012 niluu Akurẹ. Bẹẹ ni inu mi tun dun lọjọ ti mo gba awọọdu meji papọ lọjọ kan ṣoṣo, iyẹn loṣu kejila ọdun 2018 gẹgẹ bi adari ere kaakiri to peregede julọ (Best Director in Daispora) ati olugbe sinima jade kaakiri to peregede julọ (Best Producer in Daispora). Ojoojumọ ni ayọ n kun ọkan mi tori pe ọpọ la jọ bẹrẹ ti wọn ti fi iṣẹ tiata silẹ, ti emi si n tẹsiwaju pẹlu oore-ọfẹ Ọlọrun.
AWỌN TI MO TI BA ṢIṢẸ PỌ
Mo fẹẹ le sọ pe gbogbo awọn oṣere tiata patapata ni mo ti ba ṣiṣẹ pọ, mi o le maa ka wọn tan tori pe wọn pọ rẹpẹtẹ, ṣugbọn ẹnikan to wun mi lati ba ṣiṣẹ ni Kunle Afọlayan, ẹni to si tun wun mi lati dari ni Jackie Apiah.

NNKAN TO GBE MI DE ORILẸ-EDE GHANA
Iṣẹ tiata lo gbe mi de ilu Ghana, ṣugbọ ti de sibẹ patapata lati maa gbe, ati pe mo ṣi n wa ni Naijiria naa. Mo ṣi wa ni Naijiria lọsẹ meloo kan sẹyin lati wa a ya iṣẹ kan, mo si tun n bọ lọjọ kẹẹdogun oṣu yi lati wa ṣiṣẹ. Bi mo ṣe n lọ ni mo n bọ. Ghana ni mo fẹẹ maa gbe pẹlu awọn ẹbi mi bayii.

IYATỌ TO WA LAARIN SINIMA GHANA ATI NAIJIRIA PAAPAA NIPA ERE IBALOPỌ
Ṣe ẹ ri nipa ti awọn oṣere tiata ti orilẹ-ede Ghana, nnkan ti mo ri ni pe, aṣa wọn ko lodi sii, tori pe aṣa awọn oyinbo ni wọn n lo. Ti ẹ ba wo sinima ti orilẹ-ede Naijiria wa nibi, ati pe awa pin si mejil, iyẹn awa oṣere tiata Yoruba atawọ oṣere tiata oloyinbo, ti ọpọ wọn jẹ ẹya Ibo, aṣa ti wọn naa, bi ẹ ba wo o, ẹ maa ri i pe ko lodi sii, ṣugbọn aṣa Yoruba ti wa lodi si patapata pe ka maa ṣi ara silẹ, ka si tun maa wọ iwọkuwọ ninu sinima. Awọn Ghana ko ka awọn nnkan wọnyi kun, aṣa oyinbo ni wọn lo. Awọn obinrin lo ni ilu Oyinbo, bẹẹ naa lo jẹ pe awọn obinrin lo ni Ghana. Ti ẹ ba wa wo o bayii, ẹ maa ri i pe awọn nnkan bayii ti dinku, nitori pe awa ti n fi aṣa wa kọ wọn pe aṣa ti wọn n lo tẹlẹ ko dara to. Ẹ ko le ri sinima Ghana ko jọ bẹẹ mọ. Ki i ṣe pe wọn ko ni awọn to n ṣagbeyẹwo sinima, iyẹn Censors Board, o wa nibẹ, kii ṣe pe ko si, ṣugbọn aṣa wọn jẹ ki wọn ka awọn sinima ibalopọ kun.

BAWỌN OṢERE TIATA NAIJIRIA ṢE N SA LỌ SI GHANA
Ki i ṣe pe owo wa ninu sinima Ghana ju ti Naijiria lọ, ṣugbọn awọn anfaani to wa nidi iṣe tiata ju ti Naijiria lọ, akọkọ ni pe, ki i ṣe pe a ṣẹṣẹ lọ maa fi owo gba ẹrọ amunawa, iyẹn jẹnẹretọ kaakiri, ina ti wa tọsan-toru, ti ki i ṣe pe ariwo jẹnẹretọ ma maa di awọn eeyan lọwọ, bẹẹ naa lo tun jẹ pe ko si awọn janduku ti wọn maa wa di i yin lọwọ pe ki ẹ fun wọn l’owo lasiko ti ẹ ba wa l’oko ere. Ẹlẹẹkẹta ni pe bi anfaani lo tun maa jẹ lati ri ọja ta kaakiri ile ti wọn ti n ṣafihan sinima ka too gbe e wa si Naijiria. Ki i ṣe pe owo kan wa nibẹ lọ titi, ṣugbọn ka jọ ko ọmọlubọ lo ja ju. Ina mọnamọna lo jẹ pataki anfaani to wa nibẹ.

AFOJUSUN MI
Afojusun mi lọdun marun si asiko yi ni lati de ipele ti ẹni ti mo n wo gẹgẹ bi awokọse mi, ọgbẹni Kunle Afọlayan ti de, tori pe o ti gbe sinima ile Adulawọ larugẹ kọja oju tọpọ awọn eeyan fi n wo o, bo tilẹ jẹ pe emi naa ti n gbiyanju agbara mi. Emi ni oṣere tiata Yoruba akọkọ to maa kọkọ ṣafihan sinima Yoruba nilẹ Ghana. Ọjọ Mọnde Ajinde to kọja yi, iyẹn ọjọ kejilelogun osu kẹrin ọdun yi ni mo ṣafihan sinima naa, nitori naa mo fẹ gbe aṣa ati iṣe Yoruba jakejado agbaye, ki awọn ye maa fi oju onijibiti wo wa, tori pe kaakiri agbaye, oju oni jibiti ni wọn fi n wo wa. Erongba ati afojusun mi niyẹn lọdun marun un si asiko yi.

MI O PINU LATI FIṢẸ TIATA SILẸ NIGBA KANKAN
Kọ sẹni ti ko ni i fiṣẹ silẹ nigba kankan, bi eeyan ko fiṣẹ silẹ, iṣẹ a fi eeyan silẹ lọjọ kan, ṣugbọn mi o ni erongba lati fiṣẹ yi silẹ, idi ni pe mo ni awọn ipinu ti mo ti ṣe funra mi atawọn ọmọ mi. Bi awọn ọmọ mi ṣe ti de ni wọn ti ni orukọ itage (production name), to si jẹ pe ninu oṣu kẹfa yi, awọn naa maa gbe nnkan jade pẹlu orukọ itage wọn, Merry Twins. Bi mo ba dagba nibi ti mo ba de, awọn ọmọ mi a le tẹsiwaju. Bi ẹ ba wo baba mi, Ọga Bello, wọn ko le ronu lati fi iṣẹ yi silẹ, awọn ọmọ wọn ti gbe ki wọn to o gbe e de ibi tawọn ba ba a de> Oloogbe Adelove naa gbe de ibi kan kawọn ọmọ wọn to o gbe. Ti n ba dagba debi ti agba n de, orukọ mi a ṣi wa ninu iṣẹ yi.

BI MO ṢE N KOPA LAARIN AWỌN OLOLUFẸMI TO JẸ OBINRIN OBINRIN
Ko si nnkan ta a fẹ ṣe ju pe ka gba wọn mọra, tori pe awọn gan an ni wọn n mu ori wa wu. O mu mi ranti lọdun diẹ sẹyin, bi ọdun 2011, ọkan lara awọn ololufẹ mi ti jẹ ki n padanu obinrin ti mo fẹẹ fi ṣe iyawo. Ẹni ti mi o ri ri, ti o mọ ri, a lọ sọri ayelujara abanidọrẹ ti Facebook mi, a maa lọ da si ọrọ mi, to si tun ma maa fifẹ han si mi nibẹ, to fi da wahala silẹ laarin emi ati ololufẹ mi. Ati pe ka dupẹ lọwọ ẹni to ri wa to mọju, ọpọ awọn eeyan ni wọn ko wo ibi ti a wa. Lai si awọn ololufẹ wa, a ko le da awọn sinima wa wo, afi ka maa gba wọn bi wọn ba ṣe ri.

ỌRỌ MI SAWỌN OLOLUFẸ MI ATAWỌN TO FẸẸ ṢIṢẸ TIATA
Mo fẹẹ dupẹ lọwọ Ọlọrun atawọn ololufẹ mi nitori pe bi ko ba si awọn ni, ko le si ẹni to n jẹ Adekọla Ọjelere. Mo si fẹ ki wọn mọ pe gbogbo awọn nnkan ti wọn ti n ri lati ọwọ mi lati ẹin wa, ifaara lasan ni, awọn nnkan meremere ṣi n bọ lọna. Ni tawọn to fẹ ẹ darapọ mọ iṣẹ tiata, wọn gbọdọ kọkọ mọ idi ti wọn ṣe fẹẹ ṣe e, to ba jẹ pe nnkan to n fun layọ ni, ko tubọ tẹpa mọ ọn, ko si maa fi itara ṣe e. Mo dupẹ lọwọawọn to n gbe iṣẹ fun mi pe oke ni wọn yoo maa lọ, wọn ko ni i ri ibajẹ laye wọn.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI