WỌN N FI IDAJI MILIỌNU NAIRA WA ỌLỌPAA TO SALỌ NITORI ẸSUN APANIYAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 11, 2019

WỌN N FI IDAJI MILIỌNU NAIRA WA ỌLỌPAA TO SALỌ NITORI ẸSUN APANIYAN

Ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Abia ti gbe obitibiti owo silẹ pe ẹni to ba ba wọn ri ọlọpaa kan, Sajẹnti Collins Akpugo ti wọn fẹsun ipaniuyan kan lọjọ kẹrin oṣu yi ni yoo jẹ anfaani naa.

Idaji miliọnu kan naira ni Kọmiṣana ọlọpaa, Ene Ọkọn ṣeleri ẹ fun ẹnikẹni to ba kofiri Collins Akpugo, nitori pe ko sibi tawọn ko tii wa de.

Ki i ṣe pe wọn dee de gbe owo naa silẹ fawọn to ba lesọ ibi ti Collins, bi ko ṣe pe anfaani ọjọ marun un ti wọn fun un lati fi yọju, ko si wa a jẹrin gbe ara rẹ, eyi ti ko ṣe dasiko ti a ṣakojọpọ iroyin yi tan, to si mu ki wọn maa fi owo wa kaakiri.

Lọjọ Tuside ọsẹ to kọja la gbọ pe Collins yinbọn pa ọkunrin kan ti wọn pe ni Chukwuikem Onuọha, latari ọrọ to ṣebi ọrọ laarin wọn lagbegbe Afaraukwu to wa nijọba ibilẹ Umuahia North.

Wọn ọrọ ina mọto lo da wahala silẹ, ti Colloins si fibinu fa ibọn yọ lojiji, to si yin in pa oloogbe naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI