Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Muhammadu Buhari ti buwọ́lu
àbádofin láti sọ June 12 di àyájọ ọjọ́ ìjọba àwa ara wa lórilẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Sáájú àsìkò yìí ni gbogbo ìhà Iwọ-òòrun -Guusu
Nàíjíríà ti rí June 12 gẹ́gẹ́ bíì ayájọ ọjọ ìjọba àwa arawa, tí wọn si n ṣe
ajọyọ rẹ̀.
Sùgbọ́n lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ atótónú láti ọdọ àwọn ọmọ
Nàìjíríà, ààrẹ Muhammadu Buhari, lọdun tó kọja kéde pé Nàìjíríà yóò ma ya June
12 sọ́tọ̀, láti fi ṣe àyájọ ọjọ ìjọba àwa ara wa, bákan náà ni ile ìgbìmọ
aṣofin jan abádofin náà lóntẹ.
Ààrẹ Buhari tún fún Abiola ati ẹbi rẹ̀ ni àmi ẹ̀yẹ
ní Abuja, tí ìjọba tún tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ ẹbí Abiọla lórí ìjájkulẹ̀ June 12.
Kíni ìdí ti June 12 fi ṣe pàtàkì sí ẹkùn Iwọ-òòrun
Guusu Nàíjíríà:
Ní ọjọ́ Kejila oṣù Kẹfa ọdun 1993, ní ẹ̀yá Yoruba
gbà pé, ìjọba awa ara wa wọle tọ wa ni Naijiria, lẹ́yìn ìdìbò ti wọ́n gbàgbọ́
pé kò ni ẹja ń bakan, nínú ìtàn orílẹ̀ ede Nàìjíríà.
Moshood Kashimawo Abiola jáde láti di ààrẹ
orilẹ̀-èdè Naijírìa, ti Bahir Tofa náà si ta ko o latinu ẹgbẹ oselu miran,
Abiola ri ìbò tó pọ láti ìhà Arewa, bákan náà ní wọn dibo fun ni iha Iwọ-òòrun
Guusu nítori pe ó jẹ Yoruba.
Eyìn o rẹyin, Abiola ti léwáju ninu ìdìbò náà ní
ìpínlẹ̀ Mọ́kandínlógun nígbà ti Tofa bori ibo ní ìpínlẹ̀ mọkanla, Sùgbọ́n ààrẹ
ológun nigbà náà, Ọ̀gágun Ibrahim Babangida wọgile ìdìbò náà, kí wọn to ka èsì
ìdìbò naa tan.
Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán June 12 declaration: Àjọ eléto
ìdìbò gbọdọ̀ kéde MKO Abiola bí ààrẹ Nigeria
Lẹ́yìn èyí, ní wọ́n mu Abiola si atimọle tí ọ̀pọ̀
ọmọ Nàìjíríà sì gba ìgboro láti fẹ̀honu han ní ìpínlẹ̀ Eko àti Abuja pé kí wọ́n
fi Abiola silẹ̀ lẹ́wọ̀n nítori pé wọ́n ni ìgbàgbọ pé òun ló jáwe olúbori nínú
ìdìbò náà.
Ní ọ̀jọ̀ keje oṣù keje ọdún 1998 tí ó yẹ ki Abiola
jáde kúrò lẹ́wọn ni òkìkí ikú rẹ̀ kan, èyí tún fa ìfẹhonu hàn míràn.
Láti ìgbà yìí ní àwọn ènìyàn ti ya June 12 sọ́tọ̀
láti máa'fi ṣe àyájọ ìjọba àwa ara wa.
Ó dàbi ẹni pé ìgbésẹ̀ Ààrẹ Buhari kò tii tó, Kini
NADECO tún fẹ?
Nígbà ti BBC Yoruba bá àkọ̀wé gbogbo-gboo fún
àgbájọpọ̀ ẹgbẹ́ àwọn to ń ja fun ìjọba awa ara wa (NADECO), Ayo Opadoku
nsọ̀rọ̀, o sàlàyé pé, ìgbẹ́ṣẹ̀ ààrẹ ko tíì kún ojú òṣùwọ̀n to ǹkan ti àwọn ń
fẹ.
Ayo Ọpadokun ni, ó ti pẹ́ ti àwọ́n ti ń bèèrè fun JUne
12 gẹ́gẹ́ bi àyájọ ọjọ́ ìjọba awa ara wa, nítori pe ọjọ náà ni gbogbo Nàìjíríà
gbà pé ìdìbò àwọn ló gbé Abiola wọle.
O ní ìjọba olọgun ló de, to ba gbogbo ètò ìṣèjọba
Nàìjíríà jẹ́ gẹ́gẹ́ bi ìlàna ìwé ofin, nítori pe ẹyàmẹya ló pa Nàìjíríà pọ, kìí
ṣe ẹ̀yà kan náà.
Kò yẹ ki ìjọba àpàpọ lágbára lóri ìjọbá ìpínlẹ̀
nígbà ti wọn dé, èyí si ni ó gba àgbà lọ́wọ́ àwọn gómìnà ìpínlẹ̀, àti pé ìjọba
kò ti ṣe òun ti ó tọ, ti wọ̀n ò bá pàdà sí ìgbà ti àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ ba ní
akoso ohun to tọ si wọn, láti fí mú ìdàgbàsóke bá ìpínlẹ̀ wọ́n láì kọ́kọ́ lọ si
Abuja.
Nǹkan ti NADECO ń bèèrè fún:
- O pọndandan ki ààrẹ Buhari múra láti jẹ ki àwọn ẹ̀ya ti gẹ̀ẹ̀sí fún ni àgba ti sọ awọn ẹya to ku di olùwòran, nítori náa kí ààrẹ pe ìpàdé pajawiri ki àwọn ẹyà gbogbo pe ìpàde láti le yan aṣoju ti yóò ma sojú wọ́n
- O pọ́ndandan ki ààrẹ Nàìjíríà lo iwe ofin ọdun 1960 (Independent Constitution) láti fi ṣe àgbákalẹ̀ àwọn òfin tuntun ti yoo mú Nàìjíríà wà ni ìsọkan, ti à ó si fi dá orilẹ̀-èdè tuntun sílẹ̀
- Kí ààrẹ ṣe èyí láti dena ki àwọn tó ń fẹ wọ ìjọba ma ni ààfàni láti maa kó ọ̀rọ̀ gbogbo ẹyà tó ku sí ààpò tiwọn nikan, àti àwọn ololufẹ àti àwọn ọmọ wọn bí àpẹrẹ bi Abacha ṣe ko owo Naijiria lo oke okun
- NADECO tún pè fún ìdápada ètò ìjọba awa ara wá nítori pe ètò ìjọba to ń lọ lọ́wọ́ yìí jẹ ti ìjọba ọlọgún, èyí ti ó gbé àgbára fún ìjọba àpapọ̀
- NADECO tún fí kun pé, ó ṣe pàtàkì kí ààrẹ pàsẹ fún àjọ elétò ìdìbò láti kéde pé, Abiola lo jáwe olúbori nínú ìdìbo tó wáyé ní àsìkò náà, nítori pe èyí yóò mú ki àwọn ènìyàn dunnu si igbésẹ̀ ààrẹ, kí fótò Abiọla si wa ninu awọn ti won ti se ìjọba
- Bákan náà ni pe kí wọ́n fún Kudirat Abiola ni oye to ga julọ lórilẹ̀-èdè Nàìjíríà.
No comments:
Post a Comment