NIBI TI IYAALE ILE TI N KỌ MỌTO WA LO TI FI PA ỌLỌKADA DANU L'EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, June 3, 2019

NIBI TI IYAALE ILE TI N KỌ MỌTO WA LO TI FI PA ỌLỌKADA DANU L'EKOO

Ọlaide Ọṣinuga, Eko

 
Ariwo ati ẹkun ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu awọn ara agbegbe Satelite-Town niluu Ekoo laarọ onii, Mọnde nigba ti wọn sọ pe iyaale ile kan ti a ko mọ orukọ dasiko ta a kọ iroyin yi tan fi mọto paayan, to si tun salọ.

 
AWIKONKO gbọ pe ikorita kan ti wọn n pe ni Nẹpa lagbegbe Satellite-Town niṣẹlẹ ibanujẹ naa ti waye. Ohun ta a tun gbọ ni pe obinrin naa ti wọn ni ṣe lo ṣẹṣẹ n kọ mọto wiwa, to si ti kọkọ fi mọto ẹ ti wọn pe ni NISSAN SUV gba awọn meji kan lori ọkada, ṣugbọn ti ori ko awọn yẹn yọ lọwọ iku ojiji.

 
Bo tun ṣe kuro nibẹ la gbọ pe o tun lọọ fi gba ọkada min in, to si jẹ pe ẹni ti ọlọkada naa gbe gẹgẹ bi ero sẹyin to padanu ẹmi ẹ.

 
Loju ẹsẹ tiṣẹlẹ naa waye la gbọ pe obinrin naa ba ẹsẹ rẹ sọrọ, ṣugbọn ta a gbọ pe awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori ẹ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI