KO SI IBẸRU FẸNIKẸNI LASIKO AYẸYẸ ỌDUN ITUNNU AAWẸ - ẸGBẸ ALAABO SO SAFE F'ỌKAN AWỌN ARAALU BALẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, June 3, 2019

KO SI IBẸRU FẸNIKẸNI LASIKO AYẸYẸ ỌDUN ITUNNU AAWẸ - ẸGBẸ ALAABO SO SAFE F'ỌKAN AWỌN ARAALU BALẸ

Olori ẹgbẹ alaabo SO-SAFE nipinlẹ Ogun, Ọga Agba Sọji Ganzallo ti fọkan gbogbo ọmọ ipinlẹ naa balẹ pe ko ni i si wahala kankan lasiko ati lẹyin ọdun Itunnu Aawẹ to fẹẹ waye, tori pe gbogbo eto lati mu ki aabo to peye wa fun ẹmi ati dukia awọn araalu lawọn ti pari.

Ọga-Agba Ganzallo lo sọrọ naa ninu atẹjade ti agbẹnusọ ẹgbẹ alaabo naa, Ọgbẹni Mọruf Yusuf gbe jade lọsan oni, eyi ti ẹda ẹ tẹ AWIKONKO lọwọ lo ti jẹ ko di mimọ pe gbogbo eto lo ti wa ni sẹpẹ kaakiri ipinlẹ naa fun aabo ọdun.


Ganzallo ṣalaye pe lati ọjọ Aiku, Sande, ọjọ keji titi di ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹjọ oṣu yii lawọn oṣiṣẹ alaabo naa yoo ti wa lati pese aabo fawọn to ba fẹẹ rin irin-ajo lati ibi kan lọ si ekeji, nitori  awọn mọ pe ọpọ awọn eeyan ni wọn yoo fẹẹ rin irin-ajo.

Ọkunrin naa tun sọ pe lati aarọ di aṣalẹ lawọn oṣiṣẹ alaabo wọn yoo fi maa wa lẹnu iṣẹ, ti wọn yoo si sọ bi nnkan ba ṣe n lọ.

Nigba to n sọ erongba wọn ti wọn fi ya ọsẹ kan gbako naa silẹ fun akanṣe iṣẹ, Ọgbẹni Mọruf sọ pe lati daabobo ẹmi ati dukia awọn eeyan, lati rii pe ko saaye fawọn to ba fẹẹ da wahala silẹ nigboro.

Bẹẹ lo ni awọn tun wa fun lati din iwa tọọgi tabi daluru ku lakooko ọdun naa. Lati rii pe awọn eeyan bọwọ fun ofin lagbegbe wọn ati lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn oṣiṣẹ alaabo mii in.

O wa fi akoko naa parọwa fun gbogbo awọn to jẹ ọga ajọ naa lawọn ijọba ibilẹ ati ijọba ibilẹ idagbasoke lati mojuto awọn oṣiṣẹ wọn lawọn akoko naa ki wọn ma ṣe faaye gba igbakugba fun wọn.

Gbogbo awọn to wa ni ẹka ọkan-o-jọkan ninu ẹgbẹ SO-SAFE Corps ni wọn sọ pe wọn ti wa ni imura silẹ tawọn ohun gbogbo ti wọn yoo lo si ti wa nilẹ ki ọdun naa le dun yungba kaakiri ipinlẹ Ogun.

O wa rọ awọn araalu lati fọwọsowọpọ pẹlu ẹgbẹ alaabo naa, kawọn naa si yẹra fawọn nnkan to le da wahala silẹ nitori SO-SAFE Corps ko nii foju silẹ kawọn kan maa da alaafia araalu ru.  

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI