NITORI ẸSUN IFIPABANILOPỌ, WỌN KỌLU AWỌN ỌMỌ NAIJIRIA NI TOGO, ILUKULU NI WỌN N LU WỌN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, June 19, 2019

NITORI ẸSUN IFIPABANILOPỌ, WỌN KỌLU AWỌN ỌMỌ NAIJIRIA NI TOGO, ILUKULU NI WỌN N LU WỌN

Bo tilẹ jẹ pe ayederu ni iroyin naa jẹ pe awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria kan ti wọn fi orilẹ-ede Togo ṣebugbe fipa ba ọlọmọge kan laṣepọ titi to fi gbẹmi min in, eyi to mu kawọn ọmọ orilẹ-ede Togo bere sii ko iya nla bo awọn ọmọ Naijiria, sib,e okodoro ti foju han bayii pe irọ lo wa nidi ẹ.

 
Ohun ta a gbọ ni pe, ọmọ orilẹ-ede Naijiria kan ni wọn lo n yan ọmọ Togo lọrẹ, ti wọn si ti n ba ifẹ wọn bọ tipẹ, ṣugbọn ṣadede ni wọn sọ pe aawọ bẹ silẹ laarin, ti wọn si tuka.

 
Wọn ni ṣe ni ọlọmọge naa lọọ purọ pe awọn ọmọ Naijiria kan lọọ fipa ba ọlọmọge Togo laṣepọ niluu Lomẹ, to si ku mọ wọn labẹ, idi ni yii ti wọn lawọn ọmọ Lomẹ fi yari pe awọn yoo ṣe gbogbo awọn ọmọ Naijiria ṣibaṣibo, ki wọn too le wọn danu.

Lẹyin iwadii la gbọ pe aṣiri tu nigba ti wọn ko le fidi ẹni to ku naa mulẹ fawọn ọlọpaa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI