LẸYIN ỌPỌLỌPỌ TO TI N WA IYAWO, AZEEZ AGORO YOO ṢEGBEYAWO LAI PẸ - IROYIN AWIKONKO

YÀJÓ-YÀJÓ
Wednesday, June 19, 2019

LẸYIN ỌPỌLỌPỌ TO TI N WA IYAWO, AZEEZ AGORO YOO ṢEGBEYAWO LAI PẸ

Ọlaide Ọṣinuga, Eko

Adura lawọn eeyan to gbọ, paapaa awọn ololufẹ Azeez Ọladimeji to jẹ pe oun lo ga julọ lorilẹ-ede Naijiria n gba fun un bayii, lori bo ti ṣe pade ololufẹ ẹ to ti n wa lẹyin ọpọlọpọ ọdun sẹyin bayii.

Azeez ti wọn tun n pe ni Agoro lo ga niwọn bata ẹsẹ meje ataabọ, to si jẹ pe pupọ awọn eeyan ni wọn maa n fẹ ba a ya fọto papọ, ti wọn si fẹ ẹ ba a di ọrẹ.

Ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹluu akọroyin kan lai pẹ yi lo ti jẹ ko di mimọ pe bo tilẹ jẹ pe oriṣiriṣi ipenija ati adojukọ loun ti ba pade latari boun ṣe ga, to si ni eyi to le ju nibẹ ni ti aitete ri ololufẹ toun yoo gbe sile gẹgẹ bi iyawo.

 
Ṣugbọn ni bayii, Azeez Agoro ti jẹ ko ye awọn eeyan pe oun ti pade ololufẹ, to nifẹ oun tọkan-tọkan, ati pe ololufẹ naa lo wa a fi ifẹ han soun, toun si kẹnu ifẹ sii, to si gba lati fi oun ṣe ade ori.

Ninu ọrọ Azeez lo ti sọ pe "Ọpọ awọn ọlọmọge ni wọn n sa fun mi tori pe mo ga, fun idi eyi, ati tete ri iyawo ṣoro gidi fun mi, to si tun jẹ ipenija to ga ju lara awọn adojukọ mi.

"Mo ti ri ololufẹ mi bayii, ọkan lara awọn ololufẹ mi si, oun lo wa, to si loun fẹ maa ba mi ṣe ọrẹ, ti mo si gba fun un, ibi ti a ti n ṣe ọrẹ wa lọ ni mo dẹnu ifẹ kọọ, to si gba lati fẹ mi gẹgẹ ade ori ẹ. Bi mo ṣe n ba a yin sọrọ yi, a ti n palẹmọ fun eto mọmi-n-mọ-ẹ."

 
Bakan naa lo tun jẹ ko ye wa pe lara awọn adojukọ toun tun n ba pade ni bi ko ṣe si bata iwọn ẹsẹ oun to jẹ mẹtalelaadọta (size 53) lọja, paapaa awọn aṣọ toun n wọ gan an kii ṣe Naijiria loun ti n ra pupọ ninu ẹ.

Ọmọdun mẹrinlelogoji (44) naa tun sọ pe ko sẹni to fẹ ẹ gba oun siṣẹ lẹyin toun ti pari eto agunbanirọ nipinlẹ Bayelsa, pẹlu boun ṣe ga gogoro.

Ṣugbọn o jẹ ko di mimọ pe ọdun meji pere loun fi gba iṣẹ lọwọ ijọba ipinlẹ Eko nigba ti ko sẹni to ṣetan lati gba oun siṣẹ, ati pe ni bayii, iṣẹ karakata loun gbajumọ, bo tilẹ jẹ pe oun peregede lati ṣe oniruuru iṣẹ ijọba.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI