Kani kii ṣe pe awọn apẹja wa nitosi lonii ni, boya awọn ẹja ki ba ti pin baale ile kan jẹ nigba to bẹ sodo afara kẹta (Third Main Land Bridge) lati gba ẹmi ara rẹ lojiji, latari gbese ti wọn loo jẹ.
Ohun ta a gbọ ni pe asiko tawọn apẹja n kọja lọ lori omi ni wọn ni ọkunrin naa ta a ko tii mọ orukọ ẹ dasiko yi bẹ sinu odo, tawọn apẹjaa ko si beṣu bẹgba, ti wọn doola ẹmi ẹ.
Ọsibitu kan ti a ko tii mọ dasiko yi ni wọn sare gbe ọkunrin naa lọ, tawọn eeyan si n reti la gbọ ọrọ lẹnu ẹ, nipa idi to fi bẹ sodo, ko da a, tawọn kan sọ pe o ṣee ṣe ko lọ sẹwọn pẹluu ipinu lati gbẹmi ara rẹ.
No comments:
Post a Comment