BAALE ILE TA ỌMỌ ỌJỌ MẸTA L'ẸGBẸRUN LỌNA AADỌJỌ NAIRA - IROYIN AWIKONKO

YÀJÓ-YÀJÓ
Tuesday, June 25, 2019

BAALE ILE TA ỌMỌ ỌJỌ MẸTA L'ẸGBẸRUN LỌNA AADỌJỌ NAIRA

man arrested for selling his three dayold baby 
"iṣẹ eṣu ni, ẹ ṣaanu mi, ẹ foju aanu wo mi" lọrọ ẹbẹ ti wọn lo n jade lẹnu baale ile ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Chukwuma Enemuo nigba tọwọ ọlọpaa tẹ ẹ lori bo ṣe ta ọmọ ẹ, to jẹ ọmọ ọjọ mẹta, to si parọ fun iyawo ẹ pe ọmọ naa ti ku lẹyin to bii tan.

Ẹgbẹrun lọna aadọjọ (N150,000) naira la gbọ pe Enemuo ta ọmọ naa niluu Ozubulu, ijọba ibilẹ Ekwusigo, ipinlẹ Anambra.

AWIKONKO gbọ pe Enemuo gbimọ pọ pẹluu baba kan ti wọn pe ni Obi Chidubem, ẹni ọdun mariundinlaadọta (45), ti wọn si ta a fun Anulika Okafọr, ọmọdun mọkandinlogoji ti wọn loun ti n wa ọmọ tipẹ.

Nigba taṣiri maa tu, gbogbo bi wọn ṣe sọ pe iyawo ẹ, Oluchi Enemuo, ẹni ogun ọdun ṣe n beere oku ọmọ lọwọ ẹ ni ko ri ọró gidi kan sọ, to si jẹ awawi lasan lo n sọ, eyi lo muu gba tẹṣan ọlọpaa lọ lati fẹjọ sun, tawọn yẹn naa si bẹrẹ igbesẹ.

Lẹyin tọwọ tẹ lo ba bẹrẹ sii bẹbẹ pe ki wọn ṣe oun jẹjẹ, tori pe atijẹ lo sun oun debẹ, ati pe oun ti na diẹ lara owo toun ta ọmọ tuntun naa.

Ni bayii, awọn ọlọpaa ti gba ọmọ naa pada lọwọ ẹni ti wọn ta a fun, ta a si gbọ pe awọn ọdaran naa ko ni pẹ ẹ foju bale ẹjọ, gẹgẹ bi alukoro ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọgbẹni Haruna Mohammed ṣe fidi ẹ mulẹ.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI