NITORI IPO ỌBA ARẸSA-ADU L'ỌYỌ, WỌN NI ỌMỌBA ADEYẸYE KO TỌỌGI WỌ AAFIN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 9, 2019

NITORI IPO ỌBA ARẸSA-ADU L'ỌYỌ, WỌN NI ỌMỌBA ADEYẸYE KO TỌỌGI WỌ AAFIN

Ọla Eyitayọ, Ọyọ
Bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ lai pẹ yi ba fi le jẹ otitọ, a jẹ pe ọkunrin kan ti wọn n pe ni Ọmọba Adeyẹye Oyerinde ma fi ẹwọn gbara, pẹlu bi wọn lo ṣe n ko awọn tọọgi lati maa fi da wahala silẹ laarin ilu.

Ohun ta a gbọ ni pe ipo Ọba Arẹsa-adu tiluu Irẹsa-adu ni wọn ni Ọmọba Adeyẹye n ja si pe oun ni ọba kan, ti wọn lo si tun ti n pe ara ni Ọba fawọn eeyan, paapaa awọn ti wọn loo fẹ lu ni jibitii owo, ti wọn si lo ti n tapa si aṣẹ tilẹ ẹjọ pa fun pe ki onikaluku wọn loo so ewe agbejẹ m'ọwọ fungba diẹ.

AWIKONKO gbọ pe asiko tawọn afọbajẹ n ṣeto lati yan ẹni ti yoo rọpo Ọba ana to waja ni wọn ni Ọmọba Adeyẹye n sọ pe ko sẹni to le sọ pe koun ma di Ọba ilu naa, idi ni yi ti wọn loo fi lọọ ara ayederu ade, to si n de kaakiri pe oun ti j'ọba lai ni aṣẹ awọn afọbajẹ tabi oloye niluu lọwọ.

Ọrọ naa la gbọ pe wọn ti ko ara wọn lọ sile ẹjọ nitori ẹ, ti wọn si nile ẹjọ ti paṣẹ pe ki wọn lọọ yan eeyan lati idile ti ọba kan, iyẹn idile Ẹmiolu. Wọn ni idajọ yi ni ko tẹ Adeyẹye lọrun lo fi n wa ọna lati fi dabaru nnkan.
 
L'ọjọ Wẹside to kọja yi la tun gbọ pe Adeyẹye Oyerinde tun gba ilu naa lọ pẹlu awọn tọọgi ẹ, ti wọn si bẹrẹ sii lu gbogbo awọn ti wọn sọ pe ko gba tiẹ, ko da, ta a gbọ pe ọpọlọpọ dukia ni wọn tun bajẹ kọja afẹnusọ.

Wọn ni gbogbo iwa ti ọkunrin naa n hu, yatọ si pe o tako aṣẹ ile ẹjọ, wọn loo tako ofin ati ilana bi wọn ṣe n yan ọba niluu naa, to si ni aṣẹ ati ontẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ ninu, paapaa awọn idile afọbajẹ meji to wa nibẹ.

Agbẹjọro idile Ẹmiolu ti wọn ni Ọba kan yi, Amofin Abiọdun Julius nigba to n sọrọ kanminu lori iwa ti wọn ni Adeyẹye hu yi, to si ni bi ko ba ṣọra rẹ lati so agbejẹ m'ọwọ, yoo sun atimọle ọlọpaa kawọn too foju ẹ bale ẹjọ.

Wọn ni gbogbo ilu Arẹsa-adu ni wọn ko fẹran Ọmọba Adeyẹye Oyerinde latari awọn iwa jagidijagan ti wọn lo n hu laarin ilu, idi ni yii ti wọn ko fi gba layti fi j'ọba, ti wọn si ni gbogbo ilu ti ṣe iwọde ifẹhonu han lati fi tako o pe awọn ko nifẹ sawọn iwa to n hu.

Titi dasiko ti a kọ iroyin yi tan la ko tii ri ọkunrin ti wọn fẹsun kan yi ba sọrọ. Gbogbo akitiyan lati rii ba sọrọ lo ja si pabo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI