NITORI OBINRIN,, WỌN NI ỌLỌPAA LU CHINỌNSỌ PA NIDI ATM - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, June 26, 2019

NITORI OBINRIN,, WỌN NI ỌLỌPAA LU CHINỌNSỌ PA NIDI ATM

 
Gbogbo agbegbe Inyi lo fẹẹ le daru laarọ ana Tuside nigba ti wọn ni ọlọpaa kan ta a ko tii mọ orukọ rẹ dasiko yi fọ igi mọ ọdọmọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Chinọnsọ lori latari aawọ to wa laarinoun ati ọdọmọbinrin kan.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ọrọ kan lo ṣebi ọrọ laarin Oloogbe yi atiọdọmọbinrin kan nibi tiwọn ti lọọ gba owo ni First Bank to wa lagbegbe naa, nipinlẹ Ẹnugu.

 
Ṣadede ni wọn sọ pe ọlọpaa naa to n kọja lọ ri bi awọn mejeeji ṣe n tako ara wọn sọrọ, ko da a ti wọn lawọn to wa nibẹ gan an ti da sii pe ki wọn ni suuru funra wọn, ṣugbọn ti wọn ko gbọ.

Ohun ta a gbọ ni pe lojiji ni ọlọpaa fa igi nla yọ, to si laa mọ Chinọnsọ lori, loju ẹsẹ lo ṣubu lulẹ, to si gbẹmi min in. Ere ni wọn lawọn to wa nibẹ kọkọ pe e, ṣugbọn nigba ti wọn ni wọn ko ri oloogb yi ko tete dide ni ọlọpaa yi ti n gbiyanju lati ba ẹsẹ rẹ sọrọ kawọn to wa nibẹ too muu lati gbe e.

 
Nibẹ ni wọn ti gbe e lọ si ọsibitu to wa nitosi, ṣugbọn to jẹ pe akukọ ti kọ lẹyin ọmọkunrin ẹ.

Ọkan lara awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju ẹ to gbe iroyin na sita, ko to o tẹ AWIKONKO lọwọ lo ti fẹhonu han pe awọn iwa buruku ọwọ awọn ọlọpaa yi gbọdọ wa si opin tori pe loṣu kinni in ọdun yi ni ọlọpaa kan ṣekua awọn meji lori ọkada lagbegbe yi kan naa.

 
Gbogbo akitiyan lati ba alukoro ile-iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa sọrọ ko le fidi ẹ mulẹ lo ja si pabo dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI