ỌMỌ ONILẸ RU IGI OYIN L'EKOO, WỌN NI OGBOLOGBO AGBANIPA TUN NI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Wednesday, June 26, 2019

ỌMỌ ONILẸ RU IGI OYIN L'EKOO, WỌN NI OGBOLOGBO AGBANIPA TUN NI

Ojo Adeṣọla, afurasi ọdaran 
"Mo ti yi pada, mo ti gba Jesu, ẹ ṣaanu mi" lọrọ ẹbẹ ti wọn lo n tẹnu ogbologbo ọmọ onilẹ kan, Ojo Adeṣọla ti wọn tun fẹsun kan pe ogbologbo agbanipa to ti gbẹmi ọpọ eeyan ni nigba tọwọ ọlọpaa ipinlẹ Eko tẹ ẹ.

Ọjọ Fraide ọsẹ to kọja yi la gbọ pe ọwọ tẹ Adeṣọla ni nnkan bi aago mẹjọ aarọ lagbegbe Alagbado, ti wọn si oriṣiriṣi ibọn agbelẹrọ mẹrin ati ọta ibọn mejidinlogoji ni gba lọwọ loju ẹsẹ ninu ọkọ bọọsi to ko awọn ọmọ ẹyin ẹ sii lati lọọ ṣiṣẹ ibi.

Agbegbe Amikanlẹ lọwọ ti tẹ wọn gẹgẹ bi ọga agba ile-iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekoo, Bala Ẹlkana ṣe sọ. O ni ọmọdun marundinlaadọta ni Adeṣọla jẹ, to si jẹ ọmọ ẹgbẹ ikọ̀ alagbara kan to maa n gba ilẹ onilẹ, to si tun n ṣiṣẹ agbanipa nipinlẹ Ogun ati Eko.Loju ẹsẹ ti wọn laṣiri wọn ti tu lawọn ọmọṣẹ ẹ ti wọn jọ wa ninu mọto naa ti na papa bora, tawọn ọlọpaa ṣi n wa wọn dasiko yi.
Ninu ọrọ Adeṣọla lo ti sọ pe o lawọn to ran oun niṣẹ naa, tori pe iṣẹ toun fi n jẹun niyẹn, ati pe gbajugbaja loun nidi iṣẹ ajagungbalẹ nipinlẹ Ekoo ati Ogun.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI