NITORI OOGUN OWO, WỌN NI BAALE ILE MEJI FIPA BA ALAAGANNA SUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, June 25, 2019

NITORI OOGUN OWO, WỌN NI BAALE ILE MEJI FIPA BA ALAAGANNA SUN

 
Ọrọ buruku toun tẹrin nigba tọwọ ọlọpaa tẹ awọn ọrẹ meji kan ti wọn sọ pe wọn fipa pa ọdọmọbinrin kan ti wọn loo ni aisan aaganna sun, taṣiri wọn si tu sita, ko da a, ti wọn ti wa lọgba ọlọpaa titi dasiko ti ẹ n ka iroyin yi.

Ana tii ṣe Mọnde nilẹ-iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Anambra foju awọn ọdaran meji naa Okwuchukwu Anyanwu, ẹni ọdun mẹrindinlogoji ati Emeka Odọh, ọmọdun marundinlọgbọn han fawọn oniroyin.

Bawọn kan ṣe n sọ pe oogun owo ni wọn fẹẹ fi ibalopọ naa ṣe, bẹẹ lawọn kan n sọ pe kii ṣoju lasan, tawọn min in si n sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe asasi lo mu wọn.

AWIKONKO gbọ pe lọjọ Sande ijẹta ni nnkan bi aago mọkanla tan alaaganna naa, Nwanneka Nwaizu ti wọn lọmọdun mẹtalelogun ni wọnu ile akọku kan, ti wọn si ja a sihoho, ki wọn too fipa ba a sun.

Lẹyin ti wọn ṣe tan la gbọ pe wọn na papa bora, tọmọbinrin naa si sunkun jade sita, ko too tu aṣiri naa sita fawọn eeyan, eyi lo mu ki wọn gba tẹṣan ọlọpaa ijọba ibilẹ Oyi lọ lati fẹjọ sun.

Lẹyin iwadii, ti ayẹwo si fidi ẹ mulẹ lọsibitu la gbọ pe awọn ọlọpaa bẹrẹ igbesẹ lati rọwọ to wọn. Ni nnkan bi aago mẹta ana Mọnde la gbọ pe ọwọ tẹ wọn, lai mọ pe wọn ti n wa wọn tẹlẹ.

Agbẹnusọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ naa, Haruna Mohammed ti sọ pe awọn eeyan naa yoo foju bale ẹjọ lai pẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI