NNKAN MBẸ, ỌWỌ TẸ AWỌN OGBOLOGBO ỌDARAN NI KẸBBI, WỌN DANA SUN ỌKADA MARUNDINLỌGBỌN LẸẸKAN ṢOṢO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 29, 2019

NNKAN MBẸ, ỌWỌ TẸ AWỌN OGBOLOGBO ỌDARAN NI KẸBBI, WỌN DANA SUN ỌKADA MARUNDINLỌGBỌN LẸẸKAN ṢOṢO

Titi di asiko ti a kọ iroyin yi tan, ko tii sẹni to le sọ ibi ti ọrọ awọn ọdaran ti wọn lo n da ipinlẹ Kẹbbi laamu tọwọ tẹ laipẹ yi yoo ja sii, pẹluu ba a ṣe gbọ pe awọn ile iṣẹ eleto aabo patapata nipinlẹ naa ti fi aake kọri pe awọn nii laju silẹ, ki wọn maa yan awọn jẹ mọ.

Image may contain: 1 person 
Ohun ta a gbọ ni pe ṣe lawọn ile iṣẹ eleto aabo lẹdi apo pọ pẹluu ile iṣẹ ologun ti Ṣọja lati gbogun ti awọn ọdaran to n dawọn laamu lawọn agbegbe bii Bẹna, Jẹga, Danko ati Wasagu, ta a si gbọ pe inu igbo kijikiji kan ti wọn pe ni Gando ni wọn fi ṣe ibugbe, ti wọn tẹdo sibẹ.

Image may contain: one or more people and outdoor 
Awọn ẹsọ alaabo naa la gbọ pe wọn fun lorukọ HARBIN KUNAMA III, ti wọn si tunra mu lati gbogun ti iwa ọdaran patapata. Ṣa o, ilukulu la gbọ pe wọn lu awọn tọwọ tẹ, ta a si gbọ pe wọn tun dana sun ọkada ti ko din ni marundinlọgbọn ti wọn ri gba lọwọ wọn.

Image may contain: 1 person, smiling 
Lara awọn nnkan ti wọn tun ri gba lọwọ wọn ni:
a. 8 x AK 47 rifles
b. 2 x General Purpose Machine Guns
c. 2 x G3 rifles
d. 3 x dane guns.
e. 9 x AK 47 magazine
f. 48 x rounds of 7.62mm special ammunition.
 No photo description available.

 No photo description available.

Image may contain: motorcycle and outdoor

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI