IKUNLẸ ABIYAMỌ O, ỌMỌDUN MEJI GBE OOGUN APẸFỌN MU NILEEWE, LO BA KU PATAPATA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Saturday, June 29, 2019

IKUNLẸ ABIYAMỌ O, ỌMỌDUN MEJI GBE OOGUN APẸFỌN MU NILEEWE, LO BA KU PATAPATA

Lọjọ kẹtala oṣu yi la gbọ pe ọmọdekunrin yi ti wọn pe orukọ rẹ ni Flourish Simeon Ekwuojo Gospel gbe oogun ekuta ti wọn n pe ni Sniper mu lasiko to wa nileewe, to jẹ pe oogun apẹfọn naa lo ran an lo sọrun apapandodo.

Gbogbo awọn abiyamọ patapata latigba naa ni wọn ti gbadura pe ki Ọlọrun ma jẹ kawọn foju ri oku ọmọ wọn, depodepo pe awọn yoo fọwọ gbe ọmọ wọn sin.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, iluu Lọkọja, nipinlẹ Kogi niṣẹlẹ kayeefi naa ti waye nileewe ti wọn pe ni Hill Light, nigba ti wọn sọ pe awọn agunbanirọ kan ti wọn n ṣiṣẹ nileewe naa ni wọn rọ oogun apẹfọn sinu ike ọti ẹlẹrindodo tawọn ọmọde fẹran lati maa mu, iyẹn Bobo.

Ibeere tawọn eeyan n beere bayii ni pe 'ki ni wọn n fi oogun apẹfọn ṣe nileewe, to si tun jẹ pe inu ike Bobo tawọn ọmọde fẹran lati maa mu ni wọn rọ ọ sii?'

A gbọ pe Flourish nikan ni iya ati baba ẹ ṣi bi latigba ti wọn ti fẹra wọn, ti ọmọ naa si jẹ ẹyinloju fun wọn gidi gan an. Wọn ni bọmọ naa ṣe rii ike Bobo yi, ko si ironu meji to wa lọkan ju ko gbe e mu lọ.

Nigba to muu tan, ni wọn loo bẹrẹ sii sunkun pe ata wa lẹnu oun, ki wọn ba oun wa nnkan ṣe sii, gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ṣugbọn nigba ti wọn maa fi mọ nnkan to n ṣẹlẹ, ọmó naa ti dakẹ mọ wọn lọwọ.

Awọn to fiṣẹlẹ naa to AWIKONKO leti jẹ ko ye wa pe ileewe naa ni iya ọmọdekunrin yi ti n ṣiṣẹ to fi n ri owo, to si wo o pe anfaani ni yoo jẹ foun lati maa boju to ọmọ oun, idi ni yii to fi jẹ kọmọ naa bẹrẹ ẹkọ nibẹ.

Wọn ni baba ọmóde yi ko si nile, ati pe ko si nitosi lọjọ naa ki wọn too ransẹ pe e pe ọmọ ẹ to fi silẹ laarọ ti ku, loju ẹsẹ la gbọ pe o tẹkọ leti lati lọọ wo o, nigba to si maa de loootọ, oku ọmọ ẹ lo ba, ti wọn si sin in lẹsẹkẹsẹ.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI