O KU DẸDẸ KI CYNTHIA KẸKỌỌ JADE NI FASITI L’AYEDERU OOGUN IBA PA DANU L’ẸNUGU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 16, 2019

O KU DẸDẸ KI CYNTHIA KẸKỌỌ JADE NI FASITI L’AYEDERU OOGUN IBA PA DANU L’ẸNUGU

Iroyin ti ko dun mọ ẹnikẹni ninu ni ti ayederu oogun iba (malaria) kan ti wọn loo ṣekupa akẹkọọ ile ẹkọ fasiti tipinlẹ Ẹnugu lọjọ Fraide ijẹta, ta a si gbọ pe ipele to kẹhin ni akẹkọọ naa wa.

ESUT final year student 
Ojeh Cynthia Nnenna ni wọn pe orukọ akẹkọọ naa to rẹwa daadaa, ko da a, ti wọn lawọn ọkunrin maa n duu pe lati fẹ nigba to wa laye. Ẹka ikẹkọọ iṣiro (Accounting) ni wọn loo wa nipele to gbẹyin.

A ti ẹ gbọ pe ko pẹ to ba ọkan lara awọn ọrẹ rẹ sọrọ tan lori ikanni ayelujara ibara-ẹni-sọrọ (WhatsApp) pe oun loogun kan, ti oogun naa si n da inu oun ru niku wọle muu lọ wẹrẹ.

Ẹkunrẹrẹ bo ṣe ra oogun naa, ati bo ṣe lo o la gbọ pe o ṣalaye fun ọrẹ rẹ naa, to si sọ bi oogun naa ṣe n ko irora ba agọ ara oun ru.

Cynthia ṣalaye bi wọn ṣe juwe ogun naa fun un nile oloogun to lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI