ỌDAJU MỌLẸBI RE O, ỌDUN MẸTALA GBAKO NI WỌN FI LU ỌMỌ IYA WỌN NI JIBITI OWO - IROYIN AWIKONKO

YÀJÓ-YÀJÓ
Sunday, June 16, 2019

ỌDAJU MỌLẸBI RE O, ỌDUN MẸTALA GBAKO NI WỌN FI LU ỌMỌ IYA WỌN NI JIBITI OWO

Fidio kan to n lọ kaakiri ori ayelujara bayii ni ti ọdọmọkunrin kan to loun lo ọdun mẹtala nilẹ Europe lati maa fi ṣiṣẹ awọn to n gbe egboogi oloro lati fi ri owo jẹun, to si jẹ pe owo toun ri loun fi n ranṣẹ sile fawọn mọlẹbi oun.

Ipinlẹ Delta la gbọ pe iṣẹlẹ kayeefi naa ti waye.

Ohun ta a gbọ ni pe ọdọmọkunrin naa fun odindi ọdun mẹtala to lo loke okun lo fi n fowo ranṣẹ sile pe ki wọn ba oun kọ ile toun yoo de si, ṣugbọn nigba ti yoo pada de, awawi ni wọn n sọ lẹnu.

Pẹluu ibinu lọkunrin naa fi n sọrọ, to si n bu sẹkun sọrọ, to si fẹẹ le ya were.

Fidio naa re e o

 

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI