ỌDUN ORO: WỌN NI ILU LILU TI DI EEWỌ NILUU OGBOMỌṢỌ BAYII - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, June 14, 2019

ỌDUN ORO: WỌN NI ILU LILU TI DI EEWỌ NILUU OGBOMỌṢỌ BAYII

Bi ayẹyẹ ọdun Oro ti ṣe bẹrẹ niluu Ogbomọṣọ nipinlẹ Ọyọ bayii, ikilọ ti lọ sọdọ awọn araalu, paapaa awọn obinrin pe ki wọn gba ikilọ lati yago fun ririn loru ọganjọ ti Oro yoo fi ke kaakiri.

Onii tii ṣe Fraide ọjọ kẹrinla, oṣu kẹfa la gbọ pe ọdun naa yoo bẹrẹ titi di ọjọ Fraide, ọjọ kọkanlelogun ti yoo pari.

Ninu atẹjade ti akọwe fun Ṣọun tiluu Ogbomọṣọ, Ọgbẹni Ajamu Toyin fi sita lo ti jẹ ko di mimọ pe Oro ti yoo ke ko nii foju aanu wo obinrin to ba rinna pade Oro naa, ati pe aarin aago mejila oru si aago mẹrin idaji ni Oro naa yoo ke kaakiri, titi ti wọn yoo fi pari.

Bẹẹ lo tun jẹ ko di mimọ ilu lilu ti di Eewọ niluu naa laarin asiko ti ayẹyẹ ọdun Oro yi yoo fi bẹrẹ digba ti yoo pari.

Wọn ni kawọn to ba ṣetan lati tapa si awọn ofin wọnyii mura silẹ lati kagbako to ba yẹ

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI