OGUN WỌLUU: AWỌN FULANI TUN FẸẸ JI KABIYESI GBE LAAFIN L'ỌṢUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉFriday, June 14, 2019

OGUN WỌLUU: AWỌN FULANI TUN FẸẸ JI KABIYESI GBE LAAFIN L'ỌṢUN

Kani kii ṣe pe digbi lawọn alalẹ wa lẹyin Ọba David Ọlajide to jẹ Ọba iluu Osi niluu Akurẹ ni, tabi pe ki Kabiyesi naa ti jẹ eewọ, oṣee ṣe kawọn Fulani darandaran ti gbe e lọ, ki wọn si ti da ẹmi ẹ legbodo.

Ati pe, pẹluu bi nnkan si ṣe n lọ yi, bi ijọba ipinlẹ Ondo, paapaa ijọba orilẹ-ede Naijiria ko ba tete mura sọrọ eto aabo mẹhẹ yi, to ma kawọn Fulani yawọ ilẹ Yoruba lati jẹ gaba le wọn lori, afaimọ ko ma jẹ pe oogun abẹle min in nijọba n kọ lẹta sii.

Lọjọ Tuside to kọja yi la gbọ pe awọn Fulani daran-daran ya wọ iluu Osi to wa nijọba ibilẹ Akurẹ North, ti wọn si gba tọ Ọba David Ọlajide lẹyin loju ọna papakọ ofurufu tiluu Akurẹ.

Bẹ o ba gbagbe, agbegbe yi gan an ni wọn ti ji obinrin kan, Arabinrin Ọlawunmi Adelẹyẹ ati ọmọ ọkọ ẹ gbe lọjọ Sande to kọja, to si jẹ pe ori lo ko Kabiyesi naa yọ kuro lọwọ wọn

A gbọ pe ọjọ Tuside lọwọ tẹ ọkan lara awọn ọdaran naa lasiko ti Ọba Ọlajide lọọ gba obinrin naa kuro lọdọ awọn ọlọpaa ni wọn lawọn Fulani yi lọọ dena de wọn lati ji Kabiyesi gbe.

Nigba to n jẹri sọrọ naa, alukoro ile-iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Onodo, Ọgbẹni Fẹmi Joseph sọ pe loootọ ati pe ọwọ ti tẹ ọkan lara wọn, tawọn ṣi n gbe igbesẹ lati rọwọ to awọn yooku.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI