ỌPẸ O: ILE ẸJỌ SỌ PE KO ṢE DANDAN LATI NI IWE ẸRI AGUNBANIRỌ KẸNIKẸNI TO O LE JADE DU IPO LORILẸ-EDE NAIJIRIA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Thursday, June 27, 2019

ỌPẸ O: ILE ẸJỌ SỌ PE KO ṢE DANDAN LATI NI IWE ẸRI AGUNBANIRỌ KẸNIKẸNI TO O LE JADE DU IPO LORILẸ-EDE NAIJIRIA

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, inu idunnu ati ayọ lawọn ọdọ, paapaa awọn oloṣelu wa bayii latari aṣẹ ti ile ẹjọ giga kan to fikalẹ siluu Abuja pa laipẹ yi ẹnikẹni lo le jade du ipo to ba wu wọn loriulẹ-ede Naijiria.

Bẹẹ ni ile ẹjọ naa tun sọ pe ko pọn dandan fun ẹni to ba kẹkọọ gboye ni iwe ẹri agunbanirọ ko to o le yege lati jade du ipo to ba wuu lorilẹ-ede yii.
  
Ana, tii ṣe Ọjọbọ ni Onidajọ M. A Mohammẹd gbe idajọ naa kalẹ nigba to n ri si ẹsun ti ọkan lara awọn Sẹnetọ tẹlẹ lorilẹ-ede yi, Iyabọ Aniṣulowo fi tako Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun fun ti ibo to gbe e wọle.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI