ỌWỌ ỌLỌPAA TẸ GBAJUMỌ OLOṢELU TO FI ỌLỌMỌGE ṢETUTU OWO NI DẸLTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, June 30, 2019

ỌWỌ ỌLỌPAA TẸ GBAJUMỌ OLOṢELU TO FI ỌLỌMỌGE ṢETUTU OWO NI DẸLTA

Ṣe lọpọ awọn eeyan la ẹnu wọn silẹ, ti wọn ko fẹẹ le pa a se nigba tọwọ ọlọpaa ipinlẹ Dẹlta tẹ gbajugbaja babalawo kan to tun jẹ oloṣelu, Kings Okpako, ko da, ti wọn tun sọ pe ọkan lara awọn oloye iluu Abraka ni, ẹni ti wọn fẹsun kan pe o fi ọlọmọge kan ṣoogun owo.

AWIKONKO gbọ pe lọjọ kẹtadinlogun oṣu yi ni Henry Ikechukwu to jẹ afẹsọna ọlọge naa ti wọn pe orukọ ẹ ni Favour Ogheneyenrowho, ọmọdun mejidinlogun ranṣẹ pe e pe ko wa a ba oun, latigba naa la gbọ pe wọn ko ti rii mọ.

 
Wọn loo ti pẹ ti Henry ati Kings ti wọn tun n pe inagijẹ ẹ ni Kuti ti jọ n ṣiṣẹ buruku naa, ta a si gbọ pe ẹẹmẹta ọtọọtọ lo ti gbe obinrin Kings lati fi wọn ṣetutu.

Lọjọ keji tii ṣe ọjọ kejidinlogun la gbọ pe awọn eeyan dee de ri baagi apo nla kan lẹgbẹ titi, nitosi garaaji Ozoro niluu Abraka, ti wọn si loo da oorun buruku silẹ lagbegbe naa. Awọn to wa nibẹ la gbọ pe wọn lọọ yẹ ẹ wo, to si jẹ pe oku Favour ni wọn ba nibẹ, ti wọn ti fa nnkan ọmọbinrin ẹ lọ.

Wọn ni awọn to ri Favour pẹluu Henry afẹsọna ẹ ni wọn ta awọn ọlọpaa lolobo pe ki wọn lọọ muu daadaa, tori pe ọdọ ẹ lo wa gbẹyin, ta a si gbọ pe Maureen to jẹ ẹgbọn Favour naa tun ri wọn papọ lalẹ ọjọ naa.

Nigba tọwọ tẹ Henry, wọn ni ṣe lo kọkọ fẹ maa purọ fawọn ọlọpaa, ṣugbọn nigba tọwọ iya tẹ ẹ, wọn ni ṣe lo mu ohun ẹbẹ pe ki wọn ṣe oun jẹjẹ, tori pe Kuti lo ran oun niṣẹ de toru-toru, ti wọn si lọọ gbe oun naa nile.

Iwadii ṣi n lọ lọwọ gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI