O MA ṢE O, ALABOYUN KU SINU ỌKỌ OJU OMI TO DANU N'IKORODU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 30, 2019

O MA ṢE O, ALABOYUN KU SINU ỌKỌ OJU OMI TO DANU N'IKORODU

Bo tilẹ jẹ pe kii ṣe iroyin tuntun mọ pe ọkọ oju omi kan danu lagbegbe Ikorodu niluu Ekoo lọjọ Abamẹta ana an, ṣugbọn iroyin to tun to wa leti laipẹ yi ti fi han pe alaboyun kan naa wa lara awọn to ṣubu sinu agbami omi naa.

Alaboyun naa gẹgẹ ba a ṣe gbọ dagbere faye ko too di pe wọn ri wọn yọ. A gbọ pe agbegbe Badọrẹ ni ọkọ oju omi naa ti n ko awọn eeyan lọ sagbegbe Egbin to wa n'Ijede lọwọ alẹ, to si jẹ pe nnkan bi aago mẹwaa alẹ ni ọkọ naa danu lojiji.

 
Awọn ti ko din ni ogun la gbọ pe wọn wa ninu ọkọ oju omi naa, to si jẹ pe ni kete ti ọkọ naa danu ni wọn ti bẹrẹ sii wa awọn eeyan, ta a si gbọ pe awọn mẹrindinlogun ni wọn n wa titi dasiko ta a kọ iroyin yi tan.

Awọn mẹta la gbọ pe ori ko yọ ninu awọn eeyan naa, ti wọn ko si tii ri awọn yooku latigba ti wọn ti bẹrẹ sii wa gbogbo odo naa, ati pe ko sẹni to wọ aṣọ aabo ninu gbogbo awọn eeyan naa. 

 
Ohun to ti ẹ n ṣe ọpọ awọn to gbọ siṣẹlẹ naa ni kayeefi ni bi wọn ṣe sọ pe ẹni to ni ọkọ oju omi naa ṣẹṣẹ kuro lọdọ mẹkaniiki to n tun ọkọ oju omi ẹ ṣe ni, bo ṣe n kuro nibẹ la gbọ awọn eeyan yi rawọ ẹbẹ sii pe ko dakun gbe awọn de Egbin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI