SUPER EAGLE KAGBAKO BURUKU NILE MADAGASCAR, BALOGUN LO ṢAKOBA NLA FUN WỌN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Sunday, June 30, 2019

SUPER EAGLE KAGBAKO BURUKU NILE MADAGASCAR, BALOGUN LO ṢAKOBA NLA FUN WỌN

Agbako nla lo kọluu ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ti orilẹ-ede Naijiria lonii, nigba ti ẹgbẹ agbabọọlu Madagascar fiya manigbagbe jẹ wọn, ti ifigagbaga naa si ku si aami ayo meji si odo (2:0).

Ni kete ti ifigagbaga naa wọ iṣẹju mejila la gbọ pe awọn anjọọnu lati orilẹ-ede Madagascar ko wọnu Balogun, to si gbabọdi loju ile wọn, eyi to mu ki Lalaïna Nomenjanahary sare wa lati ẹyin to si gba bọọlu lọwọ ẹ, ko too wọ gooli Super Eagles nile gbuurugbu, to si gba bọọlu naa sawọn.

Nigba ti omi tun maa tẹyin wọ igbin Naijiria lẹnu, ṣe lawọn Madagascar tun ri bọọlu ọfẹ, iyẹn Free Kick loju ile. Carolus Andriamahitsinoro lo gba bọọlu naa, to si mu kawọn anjọọnu tun ko sinu Ighalo, toun fara gba bọọlu wọle.

Gbogbo iṣẹju to ku la gbọ pe awọn Super Eagles fi pooyi lori papa, ṣugbọn ti wọn ko ri nnkankan ṣe lati da aami ayo kan pada, depodepo pe wọn yoo jẹ ki ifigagbaga naa pari si ọọmi.

Pupọ awọn ọmọ Naijiria ni wọn n sọ pe ṣe lo dabi ẹni pe awọn alaṣẹ ati alakoso ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ti orilẹ-ede Naijiria ta idije to waye laarin Madagascar ati Super Eagles lonii.

Loootọ ni ikọ Super Eagles ti perege fun Round of 16 ninu idije AFCON to n lọ lọwọ lorilẹ-ede Egypt, to si jẹ pe wọn ko fi bẹẹ nilo idije naa rara.


No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI