WAHALA MIN IN TUN BẸYIN YỌ LORI IPO ỌBA AGURA TILUU GBAGURA, ABẸOKUTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Sunday, June 30, 2019

WAHALA MIN IN TUN BẸYIN YỌ LORI IPO ỌBA AGURA TILUU GBAGURA, ABẸOKUTA

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta

Bo tilẹ jẹ pe latigba ti Ọba Halidu Adedayọ Ọlaloko to jẹ Agura tiluu Gbagura ana ti waja lọjọ kẹtala oṣu keje ọdun to kọja ni wahala tani yoo de ori ipo naa ti wa nilẹ, tawọn idile ti ọba kan ti bẹrẹ sii gbena woju ara wọn, ṣugbọn ṣe lọrọ tun bẹyin yọ lọsẹ to kọja yi nigba tawọn idile mẹrin ọtọọtọ to wa labẹ Egiri gbe ijọba ipinlẹ Ogun, Ọba tuntun atawọn afọbajẹ to wa ni yara Ipebi lọ sile ẹjọ.

Ko si nnkan meji ti wọn loo fa wahala to n ṣẹlẹ naa bi ko ṣe ohun ti wọn sọ pe Adajọ fẹyinti Demọla Bakre ti wọn loo fipa fa ara rẹ silẹ gẹgẹ bi olori ẹbi Egiri ṣe sọ pe Ọmọba Saburee Babajide Bakre loun fẹ ko di Ọba Agura tiluu Gbagura tuntun latari pe o jẹ ọmọ ẹgbọn ẹ, ti wọn si lawọn araalu atawọn ti wọn jọ n du ipo ko faramọ.

AWIKONKO gbọ pe awọn ti ko din ni mẹrinla ni wọn n du ipo naa tẹlẹ ki wọn too ku mẹsan an, ati pe diẹ lara wọn ni: Ọmọba Akinyẹle Ṣarafadeen Ogunwọọlu ti idile Ijaade; Ọmọba Taofeek Adebayọ Ajani ti idile Jamolu; Ọmọba Saburi Ayinde Adeyẹmi ti idile Ijaade; Ọmọba Adetayọ Falilu Adeọṣun ti idile Adeọṣun; Ọmọba Saburee Babajide Bakre ti idile Jamolu; Ọmọba Sufian Ọlatunji Ṣoẹtan ti idile Jamolu, Ọmọba Akeem Abiọdun Agbaje atawọn min in.

Wọn ni ki Ọba Ọlaloko too waja ni igbimọ afọbajẹ ẹlẹni mejila ti wa nilẹ lati ṣakoso eto yiyan ọba min in, ṣugbọn ti meje ti ku ninu wọn, ti won fi ku marun un.

A gbọ pe ṣe ni Demọla Bakre to tun jẹ akọwe ẹbi Egiri fowo ra awọn igbimọ afọbajẹ naa, pe kawọn maraarun dibo yan Saburee Bakre to jẹ ọmọ ẹgbọn ẹ, oun si nikan ṣoṣo ni Demọla Bakre fi ọna alumọkọrọyi mu orukọ rẹ wọle fawọn afọbajẹ lai si tawọn mẹjọ to ku nibẹ.
Ọmọba Ogunwọọlu
Lẹyin ẹ la gbọ pe awọn idile Egiri fogun ta pe awọn ko yan Demọla Bakre gẹgẹ bi olori ẹbi tabi aṣoju wọn nidi ọrọ ọba ti wọn n du naa. Eyi ni wọn loo mu awọn mọlẹbi naa lọọ ṣepade lagboole Egiri to wa ni Oke-Ido, Gbagura niluu Abẹokuta lati rii pe wọn yọ Demọla Bakre, ṣugbọn ti wọn loo sọ pe ko sẹni to le yọ oun nipo naa, latari madaru ti wọn loo fẹẹ ṣe.

A ti ẹ gbọ pe ṣe ni Demọla naa ko awọn ọlọpaa atawọn babalawo kan lọ si Aafin Gbagura lati yẹ Ifa wo lori ẹni ni ti yoo j'ọba naa, ti wọn si loun atawọn ti wọn jọ n da ilu naa ru ni wọn wa nibẹ, lẹyin ẹ ni wọn loo jade sita, to si kede pe Saburee Babajide ni Ifa mu pe yoo j'ọba naa lai si awọn adije yooku nibẹ.

Awọn ta a gbọ pe wọn tọwọ bọ'we pe ki wọn yọ ọkunrin naa ni Ọmọba Adeọla Adeyẹmi ti mọlẹbi Ijaade; Ọmọba Waheed Adeọṣun to jẹ akọwe mọlẹbi Egiri; Ọmọba Sufian Ṣoẹtan ti idile Jamolu; Ọmọba Adam Ọpẹloyẹru ti idile Abọlade; ati Imaamu Jamiu Ogunwọọlu ti idile Ijaade.

Ninu awọn iwe ẹsun ti wọn fi gbe ijọba ipinlẹ Ogun, Adajọ fẹyinti naa, Demọla Bakre, Ọba tuntun naa, awọn adele ọba, awọn afọbajẹ, atawọn min in lọ sile ẹjọ, eyi to tẹ wa lọwọ lopin ọsẹ to kọja yi ni wọn ti sọ pe ọna ti wọn fi yan Ọmọba Saburee Bakre ni ko ba ilana bi wọn ṣe n yan ọba tuntun niluu Gbagura mu, to si tun tako ofin yiyan ọba nipinlẹ Ogun.

Ọmọba Ṣarafadeen Ogunwọọlu, Ọmọba Saburi Adeyẹmi, Ọmọba Sufian Ṣoẹtan, Ọmọba Salihu Adetunji Nasir, Ọmọba Kabiru Abọlade ati Ọmọba Wasiu Adeyinka ni wọn pe ẹjọ naa ti nọmba rẹ jẹ AB/292/2019 pe bijọba ko ba gbe igbesẹ lati da awọn to wa nidi madaru naa lọwọ kọ, o ṣee ṣe ko ṣakoba fun idagbasoke ilu lọjọ iwaju, ati pe wọn gbọdọ fi tawọn alalẹ ṣe.

Awọn olupẹjọ naa ninu iwe ẹsun yi tun n beere pe nibo gangan ni ile baba Demọla Bakre ati Saburee Bakre l’Oke-Iddo, Gbagura wa, ti wọn si tun sọ fun wa pe wọn ti n wa ilẹ tabi ile lati ra fi ṣe orirun wọn.

Bẹẹ ni wọn tun sọ pe gbogbo ọba ti gomina ana, Ibikunle Amosun yan lati oṣu keji titi dasiko to fi gbe ijọba silẹ nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun ti sọ pe ki wọn lọọ jokoo sile wọn, nitori pe igbesẹ ti wọn ba yan wọn ko ba ilana oye jijẹ ipinlẹ Ogun mu, ṣugbọn ti wọn sọ pe Demọla Bakre atawọn isọngbe ẹ sọ pe ofin naa ko kan ọba tawọn.

Meji lara awọn Oloye Agura ti wọn lawọn naa ko fara mọ awọn nnkan to n ṣẹlẹ, to b'AWIKONKO sọrọ, awọn eeyan naa ti wọn ni ka forukọ bo wọn laṣiri jẹ ko ye wa pe lati nnkan bi ọsẹ mẹta sẹyin ni wọn ti gbe ofin tuntun jade pe dandan ni ki gbogbo idile to wa niluu Gbagura wa maa yọju s'ọba n'Ipebi, ti wọn si gbọdọ mu awọn nnkan bii apo raisi kan, ẹgbẹrun lọna aadọta, paali ọti ṣinaapu kan, gbogbo awọn nnkan wọnyii ni wọn si sọ pe ko gbọdọ din ni ẹgbẹrun marundinlọgọta (75,000) naira.

Wọn lawọn idile ti wọn lọ ti wọn ko mu nnkankan dani ni Demọla Bakre ko fun un laaye lati wọ Ipebi ri ọba, ti wọn si lawọn to gbe nnkan dani ni wọn n fun laaye lati wọle ri ọba.

Nigba to n tako awọn ẹsun ti wọn fi kan an, Demọla Bakre sọ pe ko si otitọ kankan ninu ẹsun ti wọn fi kan oun, ati pe oun ko lọrọ lati ba oniroyin kankan sọ, tori pe awọn ti wọn gbe ẹjọ fun wa ti gbe ẹjọ naa lọ si kọọtu.

Adajọ feyinti naa jẹ ko di mimọ pe boun yoo ba ti ẹ sọrọ, ile ẹjọ nikan loun ti le sọrọ, ṣugbọn to jẹ ko ye wa pe ṣe ni ọrọ ipo ọba ti wọn n du dabi ọrọ oṣelu ni, tori pe eeyan kan ṣoṣo ni yoo di ọba, to si jẹ pe ẹni tawọn afọbajẹ fa kalẹ niyẹn.

O tun fi ye wa pe toun yoo ba ti ẹ fa eeyan kalẹ, oun lawọn ọmọ to le di ọba, ṣugbọn toun ko ṣe bẹẹ nitori pe oun mọ ofin gẹgẹ bi adajọ fẹyinti, idi ni yii toun ko fi da si ọrọ ọba ti wọn n du rara. O ni to ba jẹ ẹnikẹni ninu awọn ti wọn n sọrọ yi ni wọn fa kalẹ, oun yoo ti wọn lẹyin, ati pe olowo lo n jẹ oye lasiko ta a wa yi, nitori pe ko sẹni to fẹẹ fi akuṣẹ joye.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI