WỌN JU KAMỌRU SẸWỌN ỌDUN MẸTALA PERE, ỌMỌ KEKERE LO FIPA BA LO PỌ - IROYIN AWIKONKO

YÀJÓ-YÀJÓ
Wednesday, June 19, 2019

WỌN JU KAMỌRU SẸWỌN ỌDUN MẸTALA PERE, ỌMỌ KEKERE LO FIPA BA LO PỌ

Ọlaide Ọṣinuga, Eko

Ọjọ Tuside ana ni ile ẹjọ giga kan niluu Eko to fikalẹ sagbegbe Ikẹja ju ọdọmọkunrin, ẹni ọdun mejilelogun, Lawal Kamọru ṣewọn ọdun mẹrinla gbako, lori bi wọn loo ṣe fipa ba ọmọdun mẹrinla kan lo pọ.

Ohun ta a gbọ ni pe lọjọ kinni in oṣu keji ọdun yi ni Kamọru ti wọn nilẹ-iṣẹ burẹẹdi lo ti n ṣiṣẹ atawọn ọrẹ rẹ mẹta kan tawọn ti na papa bora ta ọmọdebinrin naa lọ sile akọku kan to wa ladugbo Oluwaniṣola lagbegbe Ilajẹ, Bariga, ti wọn si fipa ba a lo pọ.

AWIKONKO gbọ pe ọmọdebinrin ti wọn fi pa ba lo pọ yi lo n lọ sile pẹluu aburo rẹ lẹyin ti wọn kuro ni iṣọ-oru ti wọn ṣe ni ṣọọsi ni nnkan bi aago marun kọja iṣẹju mẹẹdogun la gbọ pe Kamọru lewaju awọn ọrẹ rẹ naa lọọ dena de wọn, ti wọn si fipa mu wọn wọle akọku naa.

Ọsibitu la gbọ pe ọmọdebinrin naa laju si nigba tilẹ maa mọ, to si ṣalaye nnkan to ṣẹlẹ awọn to gbe e debẹ, paapaa awọn obi ẹ. Nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ fun wọn pe Kamọru atawọn kan ni wọn fipa boun laṣepọ.

Nigba taṣiri tu la gbọ pe awọn yooku salọ, ti ko si tii sẹni to mọ ibi ti wọn wa dasiko ti wọn fi ran Kamọru lẹwọn.

Onidajọ agba, Arabinrin Raliat Adebiyi sọ pe kii ṣe pe awọn daju Kamọru rara, ṣugbọn lati le lọọ kẹkọọ siwaju sii lo mu kawọn ni ko lọ gbatẹgun ọdun mẹtala pere, bẹẹ lo sọ pe wọn yoo yọ iye asiko ti wọn fi n gbe Kamọru wa si kọọtu kuro ninu ọdun ti yoo lo lẹwọn naa.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI