WỌN L' AWỌN EFCC ATI NDLEA TI KO AWỌN AKẸKỌ FUNAAB LỌ O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 15, 2019

WỌN L' AWỌN EFCC ATI NDLEA TI KO AWỌN AKẸKỌ FUNAAB LỌ O

Inu ibẹrubojo lawọn akẹkọọ ile ẹkọ giga fasiti ti ẹkọ ọgbin, iyẹn FUNAAB wa titi dasiko ti a fi ko iroyin yi jọ tan, latari bi wọn ṣe sọ pe awọn ajọ to n gbogun ti aṣilo egbogi oloro, NDLEA ati ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu mọkumọku, EFCC ṣe yawọ agbegbe Alabata, ti wọn si ko awọn eeyan lọ.

Ni nnkan bi aago kan si mẹta oru Tọside mọjumọ Fraide la gbọ pe awọn oṣiṣẹ NDLEA yawọ agbegbe Camp to gbajumọ daadaa, nibi tawọn akẹkọọ FUNAAB pọ ju si.
A gbọ pe bi wọn ṣe n fo fẹnsi wọni ọgba ile naa ni wọn tun n ja ilẹkun wọnu awọn yara awọn akẹkọọ, ti wọn si ko awọn eeyan to jẹ akẹkọọ ni wọn lọ pẹluu bọọsi bọginni meji.
Bi ilẹ ṣe mọ daadaa, la gbọ pe awọn akẹkọọ atawọn araadugbọ figbe ta, ti wọn si bẹrẹ sii pariwo. Wọn ni ko pẹ lawọn oṣiṣẹ EFCC naa tun gbe mọto wọn de, ti wọn si bẹrẹ sii le awọnm eeyan kaakiri adugbo naa.

Ṣaa, a gbọ pe mọto bọọsi meji lawọn naa tun fi ru awọn akẹkọọ lọ.

Titi dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan lawọn ara agbegbe naa ṣi wa ninu ibẹrubojo, ti wọn fori wọn pamọ sinu ile.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI