O MA ṢE O, WỌN BA OKU GBENGA, AKẸKỌỌ FUNAAB NINU YARA Ẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉSaturday, June 15, 2019

O MA ṢE O, WỌN BA OKU GBENGA, AKẸKỌỌ FUNAAB NINU YARA Ẹ

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta
Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi lọwọ lọrọ iku ọkan lara awọn akẹkọọ FUNAAB niluu Abẹokuta ṣi n jẹ kayeefi fawọn eeyan, paapaa awọn akẹkọọ ẹgbẹ ẹ, ti wọn si n beere pe iru iku wo lo pa a, ṣugbọn ti ko tii sẹni to le fidi ẹ mulẹ di asiko ti a fi ko iroyin yi jọ tan.

Gbenga Salawu ni wọn pe orukọ akẹkọọ naa. Ohun ta a gbọ ni pe aarọ Ọjọbọ, Tọside ijẹta yi la gbọ pe wọn deede ba oku ẹ ninu yara ẹ, iyẹni nileewe naa.

Wọn nigba tawọn ọrẹ rẹ ti wọn jọ n gbe inu ile ko tete rii, lo mu ki wọn kan ilẹkun, igba ti wọn ko gbọ ohun ẹ, ni wọn ṣe fipa ja ilẹkun ẹ wọle.

Ṣe ni gbogbo wọn kawọ mọri pe iru ki leyii. Loju ẹsẹ la gbọ pe awọn agbaagba to wa nitosi ti sọ pe ki wọn lọọ fọrọ naa to awọn ọlọpaa leti.

Gbogbo akitiyan lati ba Ọgbẹni Abimbọla Oyeyẹmi to jẹ alukoro ile-iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun sọrọ, ko le fidi iṣẹlẹ naa mulẹ lo ja si pabo dasiko ta a kọ iroyin yi tan.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI