WỌN TI JU CHRISTIANA, OGBOLOGBO ỌMỌ YAHOO SẸWỌN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Friday, June 28, 2019

WỌN TI JU CHRISTIANA, OGBOLOGBO ỌMỌ YAHOO SẸWỌN

Ile ẹjọ giga apapọ kan to fikalẹ siluu Benin, ipinlẹ Ẹdo lonii Ọjọ Ẹti ti paṣẹ pe ki ọdọmọbinrin kan ti wọn fẹsun kan pe iṣẹ gbajuẹ ori ayelujara lo fi n ko ọrọ ati dukia jọ lọọ fi ẹwọn oṣu mẹjọ pere gbara.

Onidajọ M. G. Umar lo gbe idajọ naa kalẹ fun Isaac Christiana Nkemdirim lori ẹsun kan ṣoṣo ti wọn fi kan an, eyi ti wọn loo tako ofin jibiti ayelujara, ati ṣiṣẹ owo kumọ-kumọ ti abala keedogun ipele keji (Section 15(2)(a)), tọdun 2002, to si ni ijiya labẹ ofin naa.

Wọn ni ẹsun ti wọn ka si Christiana lẹsẹ lo bẹbẹ pe loootọ, ati pe ki wọn dariji oun, tori pe oun ti yi pada, ṣugbọn ti Onidajọ naa sọ pe ko lọọ ṣere diẹ lẹwọn lati mọ bi wọn ṣe n ṣe nibẹ.

1 comment:

  1. Common, this is so incomplete news.
    Details of her offence.....????????

    ReplyDeletePÍN-IN KÁÀKIRI