OJOOJUMỌ LỌRỌ AWỌN ỌDỌ ORILẸ-EDE NAIJIRIA MA N BA MI NINU JẸ PUPỌ - ỌBASANJỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, June 28, 2019

OJOOJUMỌ LỌRỌ AWỌN ỌDỌ ORILẸ-EDE NAIJIRIA MA N BA MI NINU JẸ PUPỌ - ỌBASANJỌ

Aarẹ tẹlẹri, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti kanminu lori ipo to sọ pe awọn ọdọ orilẹ-ede Naijiria wa lasiko yi, to si ni o yẹ ki pupọ ninu wọn ti di ipo oṣelu nla-nla muu, kawọn naa si maa paṣẹ.

Oloye Ọbasanjọ lo sọrọ naa lasiko to n gbawọn ọdọ kan lalejo ninu ile ikawe ti OOPL to wa niluu Abẹokuta, nibi to ti sọ pe pupọ awọn ogowẹrẹ ti ko din ni miliọnu mẹtala ni wọn ko si nile ẹkọ, yala alakọbẹrẹ tabi girama.

Baba naa ti wọn tun n pe ni Ẹbọra Owu tun jẹ ko di mimọ pe ida ọgọta  lawọn ọdọ lorilẹ-ede yi, to si jẹ pe wọn ko tii bẹrẹ sii paṣẹ pẹluu bi wọn ṣe maa n sọ fun wọn pe awọn ni ọjọ ọla orilẹ-ede yi.

O ni ki wọn ma jẹ kawọn agbaagba maa tan wọn jẹ pe awọn ni olori lọjọ ọla, tori pe nigba toun wa lọmọdun mẹrinlelogun loun ti bẹrẹ sii gbe igbesẹ adari, to si wa si imuṣẹ ni kete to ku diẹ koun pe ọmọ ọgbọn ọdun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI