ALAAFIN ỌYỌ JU LẸTA RANṢẸ SI AARẸ BUHARI LORI ETO AABO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 22, 2019

ALAAFIN ỌYỌ JU LẸTA RANṢẸ SI AARẸ BUHARI LORI ETO AABO

Pẹlu lẹta ikilọ ti Alaafin Ọyọ, Iku Baba Yeye, Ọba Lamidi Adeyẹmi kọ ranṣẹ si Aarẹ Muhammadu Buhari lọjọ Sande ana, bi ijọba ko ba tete gbe igbesẹ to yẹ lori ẹ, a jẹ pe afaimọ ki ogun nla ma bẹ silẹ lorilẹede Naijiria, latari bi wọn ṣe lawọn Fulani darandaran ṣe n fojoojumọ pawọn eeyan kaakiri, paapaa nilẹ Yoruba.

Laipẹ yi ni Aarẹ tẹlẹri, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ fi lẹta ranṣẹ si Aarẹ Buhari, bawọn kan ṣe n gbe oṣuba kare fun Baba naa pẹluu igbesẹ naa, bẹẹ lawọn kan n bu ẹnu taẹ luu.
Ṣugbọn ni bayii, Alaafin Ọyọ ti jẹ ko di mimọ pe Aarẹ Buhari ko ṣetan lati yanju wahala awọn Fulani darandaran to n ṣẹlẹ kaakiri orilẹede yi, paapaa ilẹ Yoruba, eyi to si le mu kawọn ọmọ Yoruba yi oju pada lati ja fun ara wọn.

Ọba Adeyẹmi sọ pe ọrọ ipaniyan, ifipabanilopọ ati ijinigbe to n tọwọ awọn Fulani darnadaran wa jẹ eyi to n kan gbogbo agbaye lominu, ti Aarẹ si gbọdọ wa ojutuu sii, ko too pẹ ju.

Bẹẹ lo sọ pe ki Aarẹ Buhari gbe igbesẹ lati mu awọn eeyan naa balẹ, tori pe aabo ẹmi ati dukia awọn araalu lo yẹ ko jẹ ijọba logun, tawọn oṣiṣẹ eleto aabo to kun oju oṣuwọn wa nikalẹ, nitori naa, kijọba paṣẹ fun wọn lati ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ.

2 comments:

  1. Iku Baba Yeye o, e tete wa nnkan se si o, Aare Buhari ko fee gba awa Yoruba lowo awon Fulani e o

    ReplyDelete
  2. Ogunbunmi OlatimehinJuly 22, 2019 at 12:57 PM

    A fi ki awa Yoruba gba ara wa sile lowo awon odaran Fulani darandaran yi. Nibo ni Aare Ona Kakanfo wa o?

    ReplyDelete

PÍN-IN KÁÀKIRI