LẸTA ỌBASANJỌ SI BUHARI: ẸGBẸ IGBIMỌ ỌDỌ YORUBA LAGBAYE NI MYETTI ALLAH YOO KABUKU LORI BO ṢE FẸẸ PIN NAIJIRIA SI WẸWẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 16, 2019

LẸTA ỌBASANJỌ SI BUHARI: ẸGBẸ IGBIMỌ ỌDỌ YORUBA LAGBAYE NI MYETTI ALLAH YOO KABUKU LORI BO ṢE FẸẸ PIN NAIJIRIA SI WẸWẸ

Aarẹ ẹgbẹ Igbimọ dọ Yoruba lagbaye (Yoruba Council of Youths Worldwide), Arẹmọ Oludọtun Hassan ti sọ pe pipe ti ikọ Myetti Allah pe pe kijọba apapọ kede Aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ gẹgẹ bi ẹni ti wọn n wa, ati pe ki wọn gbe e lati fiya jẹ ẹ lori lẹta to kọ si Aarẹ Buhari lana an jẹ eyi to fi n pe ogun nla wọ orilẹede yi, to si fẹẹ pin Naijiria si wẹwẹ pẹluu ogun abẹle.

Arẹmọ Oludọtun Hassan lo bu ẹnu atẹ lu Myetti Allah ninu atẹjade to gbe sita lonii, eyi ti ẹda ẹ tẹ AWIKONKO lọwọ, to si ni gbogbo wahala ipaniyan to n ṣẹlẹ lorilẹede Naijiria lasiko yi ko ṣeyin ẹgbẹ apaniyan nni, Myetti Allah, nitori pe awọn gan an ni wọn ko wahala bawọn eeyan, paapaa ilẹ Yoruba.

O ni ọrọ abuku gba a ni Myetti Allah sọ jade nitori pe lẹta ti Oloye Ọbsanjọ kọ si Aarẹ Buhari jẹ eyi to fi n pe akiyesi ijọba sawọn ibi to ku diẹ kaato to, paapaa nipa ọrọ eto aabo.

Bẹẹ lo tun sọ pe ẹdun ọkan lo n jẹ pe ẹgbẹ ti wọn pe ara wọn ni Myetti Allah yi n ṣagbatẹru awọn Fulani Darandaran ti wọn n pawọn eeyan nipakupa, ti wọn n ji awọn eeyan, ti wọn n fipa bawọn obinrin, paapaa awọn arugbo sun. Fun idi eyi, Aarẹ ẹgbẹ Igbimọ Ọdọ ilẹ Yoruba sọ pe o yẹ kijọba apapọ yẹ ẹgbẹ buruku naa wo daadaa, ki wọn si gbe igbesẹ lori wọn, tori pe awọn gan an ni wọn n da alaafia orilẹede yi ru.

Bakan naa lo tun sọ pe bawọn Fulani darandaran ṣe pa ọmọ olori ẹgbẹ Afẹnifẹre lọsẹ to kọja yi, ko ṣeyin ẹgbẹ Myetti Allah yi, nitori naa ki ijọba Buhari tete gbe igbesẹ lati tẹle awọn amọnran Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ninu lẹta to kọ ranṣẹ sii.

Siwaju sii lo tun rawọ ẹbẹ pe ki wọn tete gbe igbesẹ lati ko awọn ẹṣọ ologun sawọn opopona kaakiri ilẹ Yoruba, eyi ti igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo sọ lasiko to ṣabẹwọ si Alagba Faṣọranti laipẹ yi lati dẹkun awọn iwa ipaniyan nilẹ Yoruba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI