ỌWỌ TẸ IFẸOLUWA, AYEDERU ṢỌJA NI SANGO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 22, 2019

ỌWỌ TẸ IFẸOLUWA, AYEDERU ṢỌJA NI SANGO

Ọjọ gbogbo ni ti ole, ọjọ kan ṣoṣo bayii ni wọn pe ti olohun, eyi lọrọ afiwe ti wọn sọ fun gendekunrin kan ti wọn lọmọdun marundinlọgbọn nni, Ifẹoluwa Ẹgbẹkẹ nigba
taṣiri ẹ tu pe ayederu ṣọja lasan ni, kii ṣe ojulowo.

Agbegbe Sango si Ijoko la gbọ pe ọwọ ti tẹ Ifẹoluwa ti wọn ni ogbologbo adigunjale inu mọto kan ti wọn n pe ni 'One Chance' ni, to si jẹ pe ko sigba toun atawọn ẹmẹwa ẹ tawọn ti na papa bora ko le ṣiṣẹ buruku wọn.

Nigba tọwọ maa tẹwọn, awọn ọlọpaa olofintoto, iyẹn 'Intelligent Response Team ni wọn ta lolobo, ti wọn si gbera lati ṣewadi wọn. Baṣiri wọn ṣe tu, la gbọ pe awọn yooku ẹ ba ẹsẹ wọn sọrọ.

Bọwọ ṣe tẹ lo bẹrẹ sii bẹbẹ pe ki wọn ṣe oun jẹjẹ, tori pe iran oun kan ko ṣiṣẹ ṣọja ri, depodepo pe ouun yoo gba iṣẹ naa, to si tun loun ji aṣọ naa lati maa fi deru ba awọn eeyan, paapaa lati maa fi jẹun.

Eyi lo mu ki wọn yẹ inu gbogbo mọto ti wọn ti rii wo, ti wọn si ba awọn ẹru ofin loriṣiriṣi nibẹ bii ibọn, aṣọ ṣọja, kaadi idanimọ ti Navy, ọbẹ atawọn nnkan min in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI