ANTHONY JOSHUA YOO PADANU SỌWỌ RUIZ LẸẸKEJI - WILDER - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, July 28, 2019

ANTHONY JOSHUA YOO PADANU SỌWỌ RUIZ LẸẸKEJI - WILDER

Gbajugbaja afẹṣẹku-bi-ojo nni, Deontay Wilder ti sọ pe ko si nnkan ti Anthony Joshua tun fẹ ẹ ṣe sii bi ko ṣe pe yoo tun padanu lẹẹkeji sọwọ Andy Ruiz nitori pe o ti gba kamu nigba ti ija akọkọ waye, ati pe to ba mura sọrọ ara rẹ, o ṣi le ta pọn-pọn.

Wilder lo sọrọ naa laupẹ yi lasiko to n ba akọroyin ere idaraya ti Sky Sports sọrọ ni ile igbafẹ Fitzroy Lodge Amateur Gym to wa niluu London, to si sọ ninu ọrọ rẹ pe ko tii tan patapata fun Anthony.
 
Ko tii tan fun Anthony. Nitori pe o ti padanu, ko tunmọ si pe o ti tan sibẹ. Ko da a, to ba ti ẹ tun pada lẹẹkeji, eyi ti mo mọ pe o maa padanu ṣaa ni.

Mi o lero wi pe o mọ idi toun ṣe padanu. Ẹẹmérin ọtọọtọ ni wọn doju ẹ bolẹ. Ninu erongba temi, o ti gba kamu.

Joshua fẹ ẹ pada lọ ọ ja ija ẹlẹẹkeji lati gba ogun ẹ pada gẹgẹ bi aṣaaju nini ija abẹṣẹku-bi-ojo lagbaye.
 
Ko jẹ iyalẹnu fun mi. Inu mi si dun fun Andy pẹlu ibi to ti wa. Bi ọpọ awa ti a n ja kaakiri, o n wa ifa tikẹẹti ni. Ibi kan ni a ti wa, ti a si n wa bi a ṣe maa tọju mọlẹbi wa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI