LẸYIN ỌJỌ MẸTALA, WỌN KO TII FI IYA SIASIA SILẸ LAHAMỌ O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, July 28, 2019

LẸYIN ỌJỌ MẸTALA, WỌN KO TII FI IYA SIASIA SILẸ LAHAMỌ O

O ti pe ọjọ mẹtala gbako bayii, ti iya ọkan lara awọn agbabọọlu orilẹede Naijiria tẹlẹri, eni to tun ti figba kan ri jẹ akọnimọn ọn gba ẹgbẹ agbabọọlu ọjẹwẹwẹ, Samson Siasia gbe, tawọn ajinigbe naa si n beere owo yanturu, ki wọn too fi silẹ.

Iya Siasia, Arabinirn Beaty, ẹni ọdun mẹrindinlaadọrin la gbọ pe wọn ji gbe lagboole Odoni to wa nijọba ibilẹ Ṣagbama ipinlẹ Bayelsa lọjọ kẹẹdogun oṣu yi pẹluu awọn obinrin meji min in ni nnkan bi aago meji oru.

Ko pẹ ti wọn ji mama agba naa gbe ni wọn pe awọn mọlẹbi, ti wọn si n beere owo lati fi gba a silẹ. Ko da, tawọn meji min in ti wọn jigbe, iyẹn Arabinrin Florence Douanana, ẹni ọdun marundinlaadọrin (65), ati ọmọ ẹ, Selekire toun jẹ omọdun mẹtadinlogun.

Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ naa, Uche Anozia ti ṣeleri pe iwadii ṣi n lọwọ lori bi wọn yoo ṣe mu awọn ajinigbe naa balẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI