ỌLỌPAA TUN BẸRẸ IGBESẸ LATI GBE DINO MẸLAYE NITORI OKU IYA Ẹ TO SIN IN - IROYIN AWIKONKO

YÀJÓ-YÀJÓ
Tuesday, July 16, 2019

ỌLỌPAA TUN BẸRẸ IGBESẸ LATI GBE DINO MẸLAYE NITORI OKU IYA Ẹ TO SIN IN

Laipẹ yi ni Sẹnetọ Dino Mẹlaye to n ṣoju ẹkun Kogi West nile igbimọ aṣofin ilu Abuja ṣe oku Mama ẹ, ti gbogbo awọn eeyan peju sibẹ, ko da a, ti gbogbo ilu mi titi lọjọ naa.

Ṣugbọn lẹyin ayẹyẹ isinku naa ni fidio kan jade sori ayelujara, eyi to ṣafihan ibi ti Sẹnetọ Dino Mẹlaye ti n na owo loju agbo lai dawọ duro fun gbajumọ olorin nni, Dọkitọ Yinka Ayefẹlẹ.

Fidio naa tan kaakiri debi pe gbogbo awọn to ri i ni wọn n sọrọ lori ẹ, ko da a, titi di asiko yi.

Ọrọ ti wọn lawọn ẹgbẹ alatako n sọ lori fidio naa lo mu kawọn ọlọpaa sọ pe awọn yoo bẹrẹ iwadii lori fọnran kan to ṣafihan bi Sẹnẹtọ Dino Melaye ti n na owo fun ilu mọn ọn ka olorin kan loju agbo.

Igbakeji alukoro fun ile iṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Ọgbẹni Adeniran Arẹmu lo sọrọ naa lasiko to n ba ileeṣẹ iroyin kan sọrọ, nibẹ lo si ti ṣalaye pe ile iṣẹ ọlọpaa yoo gbe igbesẹ to ba yẹ lẹyin to ba pari iṣẹ iwadi lori fọnran ọhun.

Ọgbẹni Aremu sọ pe o ṣe pataki lati wo fọnran finifini nitori ọpọ eeyan lo n fi ọgbọn alumọnkọrọyi gbe fidio jade lori ayelujara.

O fikun ọrọ rẹ pe ile iṣẹ ọlọpaa yoo ṣa ipa rẹ lati mọ orisun fidio ti Sẹnẹtọ Dino Melaye ti n na owo loju agbo naa.

Bọndu owo nla lo wa lọwọ Ọgbẹni Dino ninu eyi ti o ti n na olorin lowo nibi inawo oku iya rẹ nipinlẹ Kogi ninu fidio naa.

Ẹwẹ, ọjọ Abamẹta to kọ ja ni ọkan lara awọn ọga agba nile ifowopamọ Naijiria (CBN), Isaac Okorafor sọ pe ile ifowopamọ naa ti ṣetan lati fọwọ ofin mu ẹnikẹni to ba n ba owo naira jẹ nipa fifi ṣe imọri loju agbo.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI