ỌLỌPAA MEJE FIPA BA IYAALE ILE SUN L'ATIMỌLE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 16, 2019

ỌLỌPAA MEJE FIPA BA IYAALE ILE SUN L'ATIMỌLE

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, bo tilẹ jẹ pe ọlọpaa mẹfa ni wọn ti jawe fun pe ki wọn ṣi lọọ gbe ile wọn na fungba diẹ, bẹẹ niwadii ṣi n lọ lọwọ lori iyaale ile tawọn ọlọpaa meje fipa ba sun latimọle wọn.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ẹsun kan ni wọn fi kan obinrin naa ati ọkọ ẹ, Nemichand ni teṣan ọlọpaa Sardarshahar, ipinlẹ Rajasthan to wa lorilẹede India, ti wọn si lawọn ọlọpaa naa ti fiya jẹ wọn gidi pe ki wọn le jẹwọ.

Iyaale ile ẹni ódun marundinlogoji naa la gbọ pe lẹyin tawọn ọlọpaa lu daadaa, ni wọn tun bẹrẹ sii ko ibasun fun karakara, titi ti ẹmi fi fẹ ẹ jabọ lara ẹ, bẹẹ la si gbọ pe ọna ti ko bofin mu ni wọn fi mu wọn satimọle naa fun ọjọ mẹfa gbako.

Aburo ọkọ obinrin naa la gbọ pe o ṣalaye ọrọ naa sita, to si n bẹ ijọba orilẹede wọn pe ki wọn ba wọn gbe igbesẹ lori iwa buruku tawọn ọlọpaa hu naa, to si tun sọ pe lẹyin ọjọ kẹfa ti wọn ti wọn mọle ni wọn pa ọkọ obinrin naa niwaju iyawo ẹ.

Awọn ọlọpaa naa sọ pe irọ ni wọn fi kan awọn nitori pe awọn ko huwa to jọ bẹẹ rara, ati pe ọjọ kẹfa oṣu yi lawọn mu ọkunrin naa, to si jẹ pe ọjọ naa lo dagbere faye nigba tawọn gbe e lọ si ọsibitu lati gba itọju.

Ṣugbọn ni bayii, iyaale ile naa ti wa lọsibitu Jaipọr bayii, nibi to ti n gba itọju lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI