BI AARẸ ỌNA KAKANFO BA MỌ PE OUN FẸẸ JA FUN ILẸ YORUBA ... - WOLII ABIỌDUN AKANNI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, July 14, 2019

BI AARẸ ỌNA KAKANFO BA MỌ PE OUN FẸẸ JA FUN ILẸ YORUBA ... - WOLII ABIỌDUN AKANNI

Gbajugba wolii nni, Wolii Abiọdun Akanni ti gba aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams lamọnran pe bo ba mọ pe oun fẹẹ ja fun ile Yoruba pẹluu bawọn Fulani ṣe n ji awọn eeyan gbe, ti wọn si n pa wọn nipakupa kaakir ilẹ Yoruba, a fi ko pe gbogbo awọn agbaagba ilẹ Yoruba patapata jọ lati ba wọn ṣepade lori ọna ti wọn yoo gbe e gba.

Wolii Akanni tun jẹ ko di mimọ pe, bi Aarẹ Ọna Kakanfo ba si n pe awọn agbaagba ilẹ Yoruba, ko gbọdọ yọ Aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ sẹyin ninu ipade naa, tori pe jagunjagun to mọ ọna abayọ ni.

Ọmọ bibi iluu Ipobẹ, lorilẹede Bẹnin naa sọ kulẹkulẹ ọrọ ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹluu AWIKONKO niluu Ṣagamu, nibẹ lo si tun ti sọ diẹ nipa itan igbesi aye rẹ pẹluu awọn ipenija to ba pade, ko too gba iṣẹ iranṣẹ.

Ẹ JẸ KA MỌ YIN LẸKUNRẸRẸ:
Oruk mi ni Wolii Dọkitọ Innocent Abiọdun Akanni, Ọmọ Ewusi, tawọn eeyan tun n pe ni Awikonko loju ọlọrọ. Ilu Ọyọ lawọn iran mi, ṣugbọn wọn tẹle Ọranyan to tẹ Ọyọ do, awọn ni wọn jọ lọ siluu Ipobẹ lati lọ tẹ ẹ do lẹyin ogun ti wọn ja nigba naa lọhun. Abẹ orilẹ-ede olominira Bẹnin ni Ipobẹ wa, ṣugbọn awọn Yoruba lo tẹdo sibẹ, awọn naa ni wọn pọ ju nibẹ, nitori pe ọmọ ajiṣebi Ọyọ laa ri, Ọyọ ko le ṣe bii baba ẹnikẹni.

DIẸ NINU IRIN AJO AYE MI:
Inu ijọ Aguda (Catholic) ni wọn ti bi mi, ibẹ naa ni wọn ti sọ mi lorukọ. Ile ẹkọ alakọbẹrẹ ti Aguda naa ni mo tun lọ, ko pẹ ni kuro nibẹ ti wọn fi mu mi lọ si Asigbo ti mo ti lọọ pari ẹkọ mi. Mo fẹran lati maa gba bọọlu nigba ti mo wa ni kekere, mo maa n gba bọọlu fun ile ẹkọ mi, mo si tun maa n ba bọọlu ni kilọọbu nigba naa. Ẹnikan lo wa si ọdọ wa lodun 1979, ẹni naa lo beere pe ṣe mo maa tẹle oun lọ siluu Ekoo, inu mi dun, mo si gba lati tẹle lọ, Agege ni wọn mu mi lọ nigba baa, ibẹ ni wọn ba mi wa iṣẹ ti mo si ile-iṣẹ nla kan, ti mo si ṣe e fungba diẹ, ti mo tun pada siluu mi lopin ọdun naa. Igba ti mo tun maa pada siluu Ekoo, ẹlọmin in ni mo ba lọ, Custain to wa ni Ọgba ni wọn n gbe, ẹni naa lo wa ba mi wa iṣẹ si Aguda, ti wọn ti n ṣe akara oyinbo (Cake) ati oriṣiriṣi ti ẹnu n jẹ. Ko pẹ ni mo tun kuro nibẹ naa, asiko ti mo n sọ yi ni wọn na Luncheon Voucher, eyi ti ọpọ awọn eeyan ko mọ lasiko yi.

Igba to ya ni mo tun lọ si Yaba nibi ti wọn ti n sin ẹranko (Zoo), ti mo si ba wọn gbe ibẹ fungba diẹ ki n to tun pada lọ siluu mi. Ọdun 1983 ni mo tun lọ kọ iṣẹ awọn to n wa katakata (Carterpilar), ọdun ni mo fi kọ ọ, ti mo si gba iwe ẹri pẹluu ontẹ ijọba Faranse (French). Bi mo ṣe gba iwe ẹri ni wolii kan sọ fun mi pe mi o gbọdọ ṣi iṣẹ to ba kọkọ jade, ṣugbọn awọn ọrọ ti wolii yẹn sọ lo jẹ ki n gba a gbọ, iyalẹnu lo jẹ fun mi. Wọn si jẹ ki n mọ pe ṣọọṣi sẹlẹ ni wolii naa n lọ. Igba ti mo ṣe tan ni mo lọ siluu Ekoo pada, ti mo si wa iṣẹ lọ, asiko yi jẹ iṣejọba Shagari. Igba ti mi o ri iṣẹ fun ọpọlọpọ oṣu, ni wọn ba mi ri iṣẹ ọmọ-ọdọ, ti mo si gba lati ṣe e. Iṣẹ ọmọ-ọdọ yi ni mọ ṣe de ilu Ṣagamu niluu Ijẹbu lọdọ Iya Abiba Ẹlẹwa to n ta ounjẹ ladugbo Ijokun, Ṣagamu nigba naa. Ọdọ iya yẹn ni mo n gbe, lọjọ kan ni mo sun, ti mo si la ala to fi ye mi pe Oluṣọ Aguntan ni mi. Latigba ti mo ti gbọnju ni mo ti maa n wa Ọlọrun, lati mọ nipa ẹ daadaa. Ṣọọṣi ti mo n lọ nigba naa, pẹluu bawọn eeyan ṣe n ṣe nibẹ lo mu mi pada sẹyin, ti mi o si lọ ṣọọṣi mọ, tori mo ti gba pe ko si Ọlọrun.

Ala ti mo la yẹn, oju oorun ni mo ti sunkun ji, ti mo si bẹrẹ sii wa ṣọọṣi sẹlẹ kaakiri lati lọ ṣọna, ibẹ ni wọn ti sọ pe ẹni ti kii ba a ṣe sẹlẹ, ko ṣe e ṣe ki wọn ṣọna fun un. Ṣọọṣi naa jẹ olu iya ijọ wa ni Ṣagamu ladugbo Ajegunlẹ, ibẹ ni mo ti dide gba iṣẹ iranṣẹ. Wọn ko gba owo lọwọ mi, mi o mu ẹyin, mi o jẹ asejẹ ki n to gba ẹmi mimọ. Ọlọrun lo gba ẹnu mi sọrọ jade, ti mo si bẹrẹ iṣẹ naa ni pẹrẹu. Ki i ṣe lẹsẹkẹsẹ ti mo gba iṣẹ iranṣẹ ni mo bẹrẹ, ṣugbọn Iya Abiba ti mo n gbe lọdọ ẹ nigba naa, Musulumi ni, baba kan ti a jọ n gbe ile naa lo ditẹ mọ mi pe ki wọn le mi danu, tori pe ko yẹ ki n maa lọ si ṣọọṣi, idi ni yii ti ọmọ iya Abiba yẹn fi le mi jade laago meje aarọ, to da gbogbo ẹru mi sita lai gbọ ẹbẹ. Idi ni yii ti mo fi gba ṣọọṣi lọ lati lọ maa gbe. Baba Ọṣhin lo gba mi tọwọ-tẹsẹ, ti mo si gba ara wọn dide, Baba Ọṣhin lo maa n mu mi lọ kaakiri fun iṣẹ iranṣẹ, ti mo si da duro. Ipinlẹ Ondo ni mo ti bẹrẹ iṣẹ iranṣẹ mi labẹ Baba Ọṣhin

Iba Gani Adams ati Wolii Abiọdun Akanni
DIẸ LARA AWỌN IPENIJA TI MO BA PADE
Ipenija pọ loriṣiriṣi, ṣugbọn diẹ naa ni mo le mẹnuba. Igba ti mo lọ n gbe ṣọọṣi, awọn kan sọ pe ki wọn le mi danu nitori pe wọn ko mọ ibi ti mo ti wa, awọn kan ti maa n pe mi ni akudaaya, mo si ṣalaye irin ajo aye mi fun Baba Ọṣhin, ti wọn si ni ki n ma wo awọn to n sọrọ mi. Igba to tun ya, wọn tun sọ pe adura ti mo n gba ti pọ ju, ṣugbọn Baba tun sọ pe asiko lati le mi ko tii to. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe gbogbo ipenija ti mo ba pade ni mo ti bori. Ṣe ti asiko ti ẹmi ati ẹnikan ti wọn n pe ni John Ọṣhingbade jọ n pin aṣọ mẹta wọ ni ki n sọ ni, abi ti ọdun kan ataabọ ti mo fi jẹ eeso nigba ti ko si oluranlọwọ ni, ti mo si dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ọpẹ ni ọrọ naa ja si bayii.

IDI TI KO ṢE SI AWỌN BII WOLII ELIJAH, ELISHA, JESU, JOHANU PETERU TITI DE ORI AWỌN BII ỌṢỌFA, ỌSITẸLU, ORIMỌLADE, AKINDAYỌMI MỌ
A ko le ri wọn mọ, tori pe Ọlọrun lo maa n yan eeyan, kii ṣe eeyan lo maa yan ara rẹ. Eeyan le ṣe e, ki aye ri oun, to si le ma jẹ pe Ọlọrun lo yan an, ẹni ti Ọlọrun ba yan, iṣe ẹ yoo yatọ si ti gbogbo wọn, ati pe awọn nnkankan wa to maa tẹle wọn. Iṣẹ ti Ọlọrun ba ti pari ni Ọlọrun ma a mọn ọn mọ gbe wa fun wọn, ki ogo Ọlọrun le maa bu yọ, kawọn naa le ni ogo, ṣugbọ ogo naa yoo yatọ si tawọn kan ti wọn pe ara wọn. Ọpọ awọn ti wọn ba dide lati ṣiṣẹ lo jẹ pe wọn maa n ka eewọ fun wọn, ṣugbọn to jẹ pe ọlọrun lo maa n ka eewọ fawọn to ba pe funra rẹ. Bi Ọlọrun ṣe maa lo awọn to pe maa yatọ si tawọn to pe ara wọn. Ẹlomin in le l,oun ji oku dide, to si jẹ pe agbelẹrọ lasan ni, ẹlomin in le lọọ gba agbara lọdọ eṣu lati ma a fi ji oku dide tabi wo aisan san. Wọn n ṣe arọ nigba min in, wọn ṣe afọju, aimọye awọn taa ti ri nile aye yi to jẹ pe irọ lo wa nidi ẹ, ti aṣiri wọn si n tu sita. Lati jẹ ki ero le pọ ni ṣọọṣi wọn ni ṣe n ṣe e, kii ṣe nnkan ti wọn pe ni ijere ọkan niyẹn.
Ko si nnkan ti eeyan ko le pe ara rẹ, ṣugbọn bibeli naa ti fi ye wa pe nipa eso wọn la o fi mọ wọn, ati pe nipa iwaw wọn ni wọn a fi gba idajọ. Nnkan ti a n ri lasiko yi ti wa laye atijọ. Wolii eke wa loootọ, ṣugbọn emi ko le pe ẹnikẹni ni eke nigba ti ki i ṣe pe emi ni mo fun un, ti mi o mọ ọna to gba debẹ, gbogbo awọn to ba pe ara wọn ni wolii ni wolii lọdọ temi.
NIPA AWỌN TO N FI ṢỌỌṢI ALAṢỌ FUNFUN ṢIṢẸ IBI
Ijọ alaṣọ funfun dabi eto oṣelu awaarawa (democracy) ni. Ko si ẹni to le mu eeyan kan tori nnkan to ṣe, ṣugbọn awa kan le maa duu pe ki wọn ba a sọ ẹsin Kirisitẹẹni lẹnu. Ijọ mimọ ko ni ki wọn fi ọlọpaa gbe ẹnikẹni, ṣugbọn sibẹ, wọn ti sọ nnkan ti ijọ naa ko fẹ fun wa. Ko si ilana kankan lati da ijọ sẹlẹ silẹ, ati pe Baba to da ijọ yi silẹ lagbaye ti sọ pe to ba to asiko kan, ijọ yi yoo di ojule si ojule, to si ti n ṣẹlẹ bayii. Bi ẹ ba si wo o daadaa, ẹ maa ṣakiyesi pe bawọn kan ṣe n ba a jẹ to, ṣe lo tun n gbooro sii, tawọn eeyan si n wọle wa, idi to fi ri bẹẹ ni pe ijọ Ọlọrun ni, ka si wa gba wi pe ko si ẹni to le ba a jẹ, afi ẹni to ba ba ara rẹ jẹ. Ijiya to wa fawọn to n fi ijọ alaṣọ funfun ni pe wọn yoo lọ koju idajọ Ọlọrun to ba ya.
Igbesẹ ti awọn olori wa n gbe bayii ni pe ijọ ti ko ba ti si labẹ aburada kan, ofin ti n wa pe awọn ọlọpaa ni yoo wo ṣọọṣi naa lulẹ, tabi pe ko yi ṣọọṣi ẹ pada si orukọ min in. Loootọ, ko yẹ ki ijọba maa gba owo lọwọ ṣọọṣi, ṣugbọn nigba to jẹ pe owo lawọn ṣọọṣi fi n taka lasiko yi, lo jẹ kijọba naa fẹ oju sii. Awọn kan si wa labẹ akoso kan to jẹ pe ọrọ ijọ ni wọn n da si loke okun, ṣugbọn ni Naijiria wa, ajọ onigbagbọ, CAN lo yẹ ko ṣe e, to si jẹ pe nnkan ti wọn n sọ ni pe ka faramọ ara wa, Ijọ alaṣọ funfun naa ni ti wọn, eyi ti wọn pe ni OIC, ti emi na ajẹ ọkan lara awọn agbaagba ẹ, awa naa wa lara CAN.
NI TAWỌN FULANI TO GBE AGBARA WỌ KAAKIRI LORILẸ-EDE NAIJIRIA
Ọjọkijọ ti ọmọ-ọkọ ba ti n ṣe bi i wi pẹ ọmọ ale loun loju aare, ọmọ ale naa ni aare ma a pe e. Awa la sọ pe Oluṣẹgun Ọbasanjọ ko dara, ṣugbọn ni gbogbo asiko ti Oloye Ọbasanjọ lo nibẹ, o lawọn nnkan to ṣe. Ẹ wo bi orilẹ-ede South Africa ṣe ri, bi Mandẹla ṣe jiya to, wọn tun fun laaye pe ko maa ṣe ijọba lọ di asiko ti ẹlẹmin ba gba a, ṣugbọn toun funra rẹ sọ pe asiko ti to foun, oun ko le ṣe e mọ, ki wọn yan ẹlomin in, ṣugbọn ni bayii, ẹ lọ wo nnkan to n ṣẹlẹ nibẹ bayii, ẹ maa ri i pe ko dabi mọ, ti South Africa ko si dara di asiko yi mọ bii ti tẹlẹ. Bi wọn ba n sọ pe Ọbasanjọ ko ṣe daradara, eeyan ti ko ba ni ẹmi Ọlọrun lo maa sọ bẹẹ.
Ọbasanjọ ṣe daradara, to si pọ koọja afẹnusọ, bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to le rin ki ori ẹ ma min, nitori pe ko sẹni to le tẹ Naijiria lọrun rara. Bi ẹ ba wo o, diẹ lara awọn oriire ti Ọbasanjọ mu wọ Naijiria, ti a si n jẹ anfaani ẹ dasiko yi ni ẹrọ ibanisọrọ. Ẹ wo igba tawọn MTN de, o lawọn to n lo o, o si niye ti wọn n ta a siimu (SIM Card), igba to tun ya, o tun niye ti wọn n ta. Igba to tun ya, o tun ba wọn fa a titi, to si rii pe wọn ko fẹ ẹ gbọ, lo ba gbe awọn alatako dide, ti wọn si gbe ECONET dide lati ba wọn fa a, tawọn eeyan si rọ lọ sọdọ wọn. Bo tun ṣe to asiko kan, tawọn yẹn naa fẹ ẹ gbabọdi, ti wọn fẹ maa bawọn MTN fọọsowọpọ, lo ba gbe GLO dide. Okoowo ti ko ba ti si ifigagbaga, wọn maa n ṣe nnkan to ba wun wọn ni. Igba tawọn GLO de, tawọn eeyan tun rọ lọ sibẹ, paapaa ọwọ ti wọn tun gbe nigba to ya lo mu ki gbogbo ẹ bẹrẹ sii lọ silẹ.
Ṣe ni wọn n fi siimu naa bẹ wa bayii, tori pe ko le lọ soke mọ bayii. Ọgọrun naira ni wọn ta bayii, iṣẹ ọwọ Ọbasanjọ ni. Ẹlẹẹkeji, igbe aye arunpa lawọn olukọ n gbe tẹlẹ, to jẹ pe Ọbasanjọ lo gbe ‘Gbẹnu Arẹmu’ dide, tawọn olukọni di ẹni to n kọ ile ra ilẹ, ti wọn kọ ile nla, ti wọn tun n ra mọto to wun wọn. Latigba to si ti kuro nibẹ, ko sẹni to tun ri iru ẹ ṣe mọ. Eyi to tun ya mi lẹnu ninu ọrọ ẹ, to jẹ pe asiko ko to fun un lati ṣe e, ti ko ba jẹ ẹlẹẹkẹta, to ba jẹ pe kii ṣe bo ṣe jẹ, wọn a ti gba awọn min in laaye lati wọle wa koju DSTV, owo yẹn a si ti lọ silẹ ju bo ṣe wa bayii lọ. Wọn rẹ Naijiria jẹ kọja oju ta a fi n wo o. Awọn ọmọ Naijiria naa lo wa nibẹ lọdọ wọn lọhun, tori pe oyinbo ko le de lati wa a fọwọ lalẹ fun wa nibi, nigba ko mọ bi ilu wa ṣe ri. Lẹyin ẹ, Ọbasanjọ naa lo gbe EFCC dide, owo ti wọn si gba naa ni wọn lo ninu ẹ fi kọ papa iṣere to wa l’Abuja. Awọn kan n sọ pe wọn ko mọ bi wọn ṣe ṣe owo, ṣugbọn eyi tawọn Hausa wọn gba, bawo ni wọn ṣe ṣe e.
Ko si nnkan ti wọn tun ṣe to tun dọgba bii ti Ọbasanjọ mọ, ijọba di ẹni to n jẹ awọn olukọ lowo oṣu, ti wọn dẹni to n tọrọ jẹ. Ko dara rara, bibeli gan an sọ pe ‘ẹ san owo ọya fawọn to tọ si’. Awọn oṣiṣẹ a ṣiṣẹ, ijọba ko nii san owo mẹta, marun fun wọn. Ki lo de to jẹ pe igba ti Ọbasanjọ kuro nibẹ ni wọn ko san owo ọya fawọn oṣiṣẹ mọ.
Ori lo gbe Baba wa Buhari debẹ, ẹni to ba si fẹẹ tun Naijiria ṣe yoo kọkọ mojuto ile ẹ na. Bi wọn ba sọ pe ki awa Yoruba ye e gbe ibọn rin kaakiri, ki lo de tawọn Hausa n gbe ibọn ati ada rin kaakiri, wọn si n sọ pe aabo lo wa fun, ọlọpaa ko si mu wọn ri. Igba ti a fi wọn silẹ naa, ko si nnkan ti mo fẹẹ sọ bi ko ṣe pe Yoruba ni wọn ko gbọdọ gbagbe sun. Ki Yoruba pada wa sile lati ronu ara wọn, ki wọn ye e ru ofin sori bii ti harahara. Awọn iran Fulani ti pinu pe awọn ni wọn a maa jẹ olori, ki Yoruba ati Ibo maa ṣe ọmọ ọdọ lẹyin wọn.
Tori pe Yoruba ko ti i fọwọ sii pe ki Ibo maa lọ ni ko ṣe rọrun fawọn Ibo lati pin, bi Yoruba ba da si i, wọn maa kuro dandan ni. Ki onikaluku duro, kawọn Fulani, Hausa duro laaye wọn lọhun lati maa da ẹran wọn kaakiri, ki awa naa si duro laaye wa. Ko ni i si wahala, ṣugbọn ọtẹ ti a n ṣe kaakiri ni ko jẹ ka ni isinmi, ki Ọlọrun jẹ ka bọ kuro ninu ọtẹ ni.
Bẹẹ naa nipinlẹ Ogun, awọn kan ṣejọba, wọn jẹ owo oṣu lọ ni, awọn to tun ṣe ki Ibikunle Amosun to o lọ naa jẹ owo lọ ni, bẹẹ ni Amosun naa jẹ owo ko too lọ, ẹni to bọ sibẹ lonii naa, a ko ti i le sọ boun naa yo o ṣe ṣe to ba maa fijọba silẹ, ṣugbọn mo nigbagbọ pe yoo ṣe daadaa, nitori pe ki i ṣe ọmọ ale, ọmọ gidi ni Dapọ Abiọdun, o si ni itẹriba pupọ. Bia  ba sọ pe Amosun ko ṣiṣẹ, a n tan ara wa jẹ ni, ẹ lọ wo bi ilu Abẹokuta ṣe ri, talo ri Abẹokuta si olu-ilu tẹlẹ, ṣugbọn oun ni wọn n ri bayii. Pẹluu atilẹyin Ọlọrun ni Amosun fi ṣe ijọba ẹ laṣeyege. Onikaluku lo nigba ti wọn. Ọkan mi balẹ pe Ọmọba Dapọ Abiọdun yoo ṣe daradara tori pe ki i ṣe ọmọ ale Ipẹru. Bẹẹ naa lo jẹ pe kani Alagba mi, Ọnọrebu Oladipupọ Adebutu lo wọle ni, oun naa yoo ṣe daradara ju nnkan tẹnikẹni le lero lọ, tori pe alaanu mẹkunnu ni. ọnọrebu Adebutu gbiyanju agbara rẹ, o i duu titi, ṣugbọn bi aye ṣe fẹẹ niyẹn, mo si nigbagbọ pẹluu ogo Ọlọrun pe gbogbo owo to na ni ko nii lọ l’ofo. Mo si gbadura pe Ọlọrun a da gbogbo ikolọ ẹ pada pẹluu irọrun. ọlọrun a si ti i lẹyin lati debẹ.
AMỌNRAN MI FUN AARẸ ỌNA KAKANFO
Bi Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ba mọ pe oun fẹẹ ja fun ilẹ Yoruba, a jẹ pe Ọlọrun fẹ ẹ lo fun ogo kan ni, ogo orilẹ-ede si ni. Bi a ṣe bi i lo si fa, tori pe a ti bi i l’akọ ni. Akọni ni Gani Adams, to si jẹ pe Ọlọrun lo gbe e de bẹ. Mo fẹ ki Iba Gani Adams ranti pe Aarẹ Ọna Kakanfo kan lo gbe wa ṣubu nigba kan, to fi di pe awọn Fulani lo wa n paṣẹ niluu Ilọrin titi di asiko yi, Yoruba niluu Ilọrin, Ṣebi Yoruba ni Bukọla Saraki, Saraki inu orukọ ẹ ni yoo yọ kuro, yoo si jẹ ko le mọ ibi to ti wa. Bi Aarẹ Ọna Kakanfo ba mọ pe loootọ loun fẹẹ ja fun ilẹ Yoruba, o gbọdọ kọkọ pe gbogbo awọn agbaagba ilẹ Yoruba jokoo lati ba wọn ṣepade, ti Oloye Ọbasanjọ ko si gbọdọ gbẹyin nibẹ. Ọbasanjọ ti jagun ilẹ ri, ija ti a si fẹ ẹ ja yi, ki i ṣe ija ọrọ ibọn, bi ko ṣe ija abẹlẹ, ti yoo fun wa lanfaani lati lo agbara ilẹ Yoruba lati fi je, ko si wa a rawọ ẹbẹ si Ọlọrun ko le tii lẹyin.  

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI