Ọga agba ẹgbẹ eleto aabo ti
fijilante, iyẹn Vigilante Group of Nigeria, nipinlẹ Ogun, Kọmanda Ọlanrewaju
Nureni Adedoyin ti sọ pe ko si nnkan to buru ninu ka lo awọn nnkan ija ogun
tilẹ Yoruba lati fi gbogun ti awọn ọdaran ti wọn sapamọ sawọn inu igbo kaakiri
ilẹ Yoruba lati maa fi ṣiṣẹ ibi, iyẹn bawọn nnkan naa ko ba ti lodi sofin orilẹede Naijiria.
Kọmanda Adedoyin lo sọrọ naa
lọsẹ to kọja yi nibi apejọ kan to ṣe nipa eto aabo, eyi to wa nile iṣẹ wọn to
wa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.
Nibẹ lo ti sọ pe ẹgbẹ VGN nikan
lo mọ ọna abayọ si iṣoro to n koju orilẹede Naijiria nipa eto aabo nitori pe awọn
sunmọ awọn araalu ju ile iṣẹ eleto to ku, nitori naa lo ṣe n rawọ ẹbẹ sijọba
Aarẹ Buhari pe ki wọn tete bu ọwọ lu iwe abadofin ẹgbẹ wọn ko too pẹ ju.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Ki i ṣe
awọn Fulani darandaran ni wọn n sapamọ sinu igbo pa awọn eeyan, ti wọn n ji
awọn eeyan gbe, bi ko ṣe awọn ajoji ti wọn yọ kẹlẹkẹlẹ wọ Naijiria wa. Awọn
ajoji naa lo jẹ pe aṣọ Fulani ni wọn n gbe wọ, ṣugbọn wọn kii ṣe Fulani rara,
bẹẹ ni wọn kii ṣe ọmọ orilẹede Naijiria.
“Inu igbo wa ni wọn si sapamọ
si, ti wọn n fiya jẹ wa, paapaa nilẹ Yoruba. Ẹ maa ranti pe ilẹ Hausa ni wọn ti
bẹrẹ, to si jẹ pe a ko tete fura, ko tooo di pe wọn de ilẹ Yoruba. A ko fẹ ki
Naijiria to ti n jẹ anfaani ifẹ, iṣọkan ati eto aabo to peye lati ẹyin wa, wa a
di eyi ti ko nii le sun asunpajude, eyi lo jẹ ka maa rawọ ẹbẹ sijọba Aarẹ
Buhari pe ki wọn tete bu ọwọ lu iwe abadofin ẹgbẹ VGN ko too pẹ ju.
“VGN gẹgẹ bi ẹ ṣe mọ pe a mọ
tinu-tẹdọ nipa eto aabo, awa la si le e mu gbogbo ipaniyan ati ijinigbe to n
ṣẹlẹ nilẹ Yoruba, paapaa kaakiri orilẹede Naijiria wa si opin. Asiko naa ṣi wa
bayii, ko too pẹ ju.
“Bi ẹ ba wo daadaa, ẹ maa ri i
wipe wọn ko ba ti wọ inu ipinlẹ Ogun naa wa, bi ki i ba a ṣe igbiyanju wa pẹluu
ifọwọsowọpọ awọn ọlọpaa la fi loo koju wọn, ki wọn too sa pada.
“Loootọ, bi a ba wo o, awọn
baba wa sọ pe aibọwọ f’agba ni ko jẹ ki aye gun. Awọn baba nla wa si ni awọn
nnkan ti wọn fi n ṣeto aabo ko too di pe ọlaju wọle de, tawọn oloyinbo naa si
gbe ti wọn de.
“Bi a le ri awọn nnkan eto aabo
igba yẹn, ti wọn kii si i ṣe awọn nnkan to lodi sofin, ko si nnkan to buru nibẹ
bi a ba fi daabo bo ara wa nilẹ Yoruba, ṣugbọn awọn nnkan igbalode yi naa lo yẹ
ka lo lati fi jagun.
“Ki la fẹ ẹ fi wa awọn ọdaran
ti wọn sa sinu igbo, bi ko ṣe ti ẹrọ-tuna-aṣiri, iyẹn drone to n fo loke, kinni
yi lo si rin ju ohunkohun lọ, ti ko si si inu igbo ti ko le wọ lati tu aṣiri
awọn ọdaran wọnyii."
Bakan naa lo wa fi kun ọrọ rẹ pe boun ba ṣi n wa ninu eto aabo lorilẹede yi, paapaa nipinlẹ Ogun, oun ko nii gba iwa ọdaran laaye bo ti wu ko mọ.
Bakan naa lo wa fi kun ọrọ rẹ pe boun ba ṣi n wa ninu eto aabo lorilẹede yi, paapaa nipinlẹ Ogun, oun ko nii gba iwa ọdaran laaye bo ti wu ko mọ.
No comments:
Post a Comment