BI ỌRỌ MAUSTECH KO BA NIYANJU, KAWỌN AKẸKỌỌ PADA SI MAPOLY WỌN - GOMINA ABIỌDUN PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉWednesday, July 24, 2019

BI ỌRỌ MAUSTECH KO BA NIYANJU, KAWỌN AKẸKỌỌ PADA SI MAPOLY WỌN - GOMINA ABIỌDUN PARIWO SITA

Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun ti sọ pe ko si nnkan to kan oun ninu ọrọ ti wọn n gbe kaakiri nipa ile ẹkọ fasiti imọ ẹrọ ti Mọshood Abiọla, iyẹn Moshood Abiola University of Science and Technology (MAUSTECH), nitori pe awọn ọjọgbọn ti sọ eyi to jẹ okodoro nipa ẹ.

Bẹẹ lo sọ pe kawọn akẹkọọ pada sẹnu ẹkọ wọn, nitori pe nnkan to ṣe pataki lasiko yi ni eto ẹkọ, dipo ariyanjiyan to n lọ kaakiri.

O ni pẹluu gbogbo owo ati wahala tijọba ana ti na le ile ẹkọ MAUSTECH lori, pabo lo ja si, tori pe ko ṣiṣẹ titi dasiko yi, dipo bẹẹ, kawọn akẹkọọ MAPOLY pada sẹnu ẹkọ wọn.

Gomina Abiọdun sọrọ yi lasiko to n gba ẹgbẹ ọmọ bibi iluu Abẹokuta, iyẹn Abẹokuta Club lalejo ninu ọfiisi ẹ to wa ni Oke-Mọsan niluu Abẹokuta.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI