ỌWỌ TUN TẸ AWỌN ỌMỌ YAHOO MẸSAN-AN L'ẸDO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉWednesday, July 24, 2019

ỌWỌ TUN TẸ AWỌN ỌMỌ YAHOO MẸSAN-AN L'ẸDO


Iyalẹnu nla gba a lo jẹ fun ọpọ awọn eeyan nigba ti wọn gbọ pe okete awọn gendekunrin kan ti wọn ni wọn ko niṣẹ meji ju jibiti ori ayelujara, iyẹn Yahoo-Yahoo lọ, nipinlẹ Ẹdo, iyẹn iluu Benin.

Ana tii ṣe Iṣẹgun lọwọ tẹ awọn ọmọ Yahoo naa tọjọ ori wọn ko ju ogun ọdun si ọdun marundinlogoji lọ, iyẹn Amafin Collins, Edafitite Abel, Usianene Elizojie, Ojiefor Marvelus, Uduehi Osumor, Geigi Emmanuel Ose, Osaro Osakpolor, Francis Omoiegbe ati Onuoba Prince Nonso.

 
Oriṣiriṣiri ẹru ni wọn gba lọwọ wọn loju ẹsẹ, awọn ẹru bii mọto bọginni, ẹrọ kọmputa alagbeeka, foonu atawọn nnkan min in loriṣiriṣi, ti wọn sọ pe wọn ti fi lu awọn eeyan ni jibiti obitibiti owo lori ayelujara.

EFCC Arrests 
Bo tilẹ jẹ pe ohun ta a gbọ ni pe wọn ko ni pẹ ẹ foju awọn ọdaran naa bale ẹjọ, sibẹ ọga agba ẹka ajọ EFCC nipinlẹ Ẹdo, Muhtar Bello gbawọn araalu lamọnran pe ki wọn yee ya awọn eeyan ni foonu wọn lati maa lo fi ṣi imeeli, tori pe akoba ni yoo jẹ fun wọn.
EFCC Arrests
EFCC Arrests

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI