Ẹ GBA MI O, Ẹ MA JẸ KI WỌN PA MI SAHAMỌ AWỌN BOKO HARAM O - GRACE RAWỌ ẸBẸ SI AJỌ CAN ATI IJỌBA APAPỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 25, 2019

Ẹ GBA MI O, Ẹ MA JẸ KI WỌN PA MI SAHAMỌ AWỌN BOKO HARAM O - GRACE RAWỌ ẸBẸ SI AJỌ CAN ATI IJỌBA APAPỌ

Ọdọmọbinrin kan tawọn Boko Haram ji gbe lọsẹ to kọja ti pariwo sita lahamọ to wa pe kijọba apapọ orilẹede Niajiria, ati ajọ awọn ọmọlẹyin Kristi, iyẹn CAN ran oun lọwọ lati jade kuro nibẹ, nitori pe iya ojoojumọ loun n jẹ nibẹ, ati pe oun ko ṣetan lati ku iku ẹṣẹ aimọdi.

L'Ọjọbọ ọsẹ to kọja yi lawọn Boko Haram tun ṣọṣẹ lagbegbe Damasak to wa nipinlẹ Borno, ti wọn si kede lẹyin rẹ pe wọn n wa ọdọmọbinrin kan to jẹ oṣiṣẹ ajọ kan to n gbogun ti ebi, iyẹn Action Against Hunger nipinlẹ naa.

Grace nigba to n sọrọ ninu fọnran kan tawọn Boko Haram gbe jade sita laipẹ yi pẹluu aṣọ Ijaabu lori lo ti pariwo pe ki wọn ran oun atawọn mẹfa ti wọn ji gbe lọwọ lati jade lahamọ awọn ọdaran aṣekupani naa lọwọ.
Grace lorukọ mi. Mo n ṣiṣẹ pẹluu ajọ Action Against Hunger, ajọ naa to wa nipinlẹ Borno. Damasak ni mo n gbe. Ọjọbọ Tọside tii ṣe ọjọ kejidinlogun oṣu la jade lọ ṣiṣẹ, nigba ti a n pada lọ si Damasak ti a ti wa, lawọn kan ninu aṣọ ologun da wa lọna, ti wọn si ko wa wa sibi ti o ti n sọrọ yi, ibẹ naa ni mi o tii mọ dasiko ti mo n sọrọ yi.

Mo fẹ ki ajọ CAN, iyẹn Christian Association of Nigeria ran mi lọwọ, nitori pe emi nikan ni Kristẹni laarin awa mẹfa ti a wa nibi yi, nitori pe mo fẹ ki ajọ CAN gbe igbesẹ lati ri i ọna bi wọn yoo ṣe gba mi silẹ.

Mo si tun fẹ ẹ rawọ ẹbẹ si ajọ Action Against Hunger nipinlẹ Borno pe awa mẹfa la wa nibi ti a si jẹ oṣiṣẹ AAH, ibiṣẹ la lọ, asiko ti a n pada sile ni wọn ko wa. Mo bẹ ajọ Action Against Hunger tori pe awa naa ni mọlẹbi, ti awa kan si ni ọmọ nile.

Ọmọ orilẹede Naijiria yi ni wa, mo si fẹ kijọba gbe igbesẹ lati ran wa lọwọ, nitori e a n ṣiṣẹ fun Naijiria ni. Wọn mu awọn oṣiṣẹ kan naa, ti wọn si bẹbẹ fun itusilẹ, loju ẹsẹ ni wọn ti pa wọn nitori pe Naijiria ko ṣe nnkankan sii. Mo n bẹbẹ lorukọ awa ti a jọ wa nibi e ki wọn gba wa silẹ, nitori pe ko fẹ ki iru nnkan bẹẹ ṣẹlẹ si awa naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI