ỌPỌ IGBEYAWO TI WỌN N ṢE NILE IJỌSIN NI KO SI LABẸ OFIN, AYEDERU NI WỌN - IJỌBA APAPỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, July 25, 2019

ỌPỌ IGBEYAWO TI WỌN N ṢE NILE IJỌSIN NI KO SI LABẸ OFIN, AYEDERU NI WỌN - IJỌBA APAPỌ

Ijọba apapọ orilẹede Naijria ti jẹ ko di mimọ pe pupọ ninu awọn igbeyawo asiko yi lo jẹ pe ayederu ni wọ, nitori pe wọn si ṣe wọn labẹ igbeyawo orilẹede yi.

Ọjọru Wẹside ana nijọba apapọ kede ọrọ yi, to si sọ pe ẹgbẹrun lọna ọọdunrun ati mẹrinla (314) pere lawọn ile ijọsin tijọba fun niwe aṣẹ lati maa so tọkọ-taya papọ nibamu pẹluu ofin.

Nigba to n sọrọ nibi ipade gbogboogbo kan to waye, Amofin Georgina E. Ehuriah sọ pe "Bi mo ṣe n sọrọ yi, ẹgbẹrun mẹrin ataabọ (4, 689) lawọn ile ijọsin ti wọn ti gba niwe aṣẹ, to si jẹ pe awọn 314 pere ni wọn ti tun iwe wọn ṣe labẹ akoso ileeṣẹ  Ministry of Interior.

"Atubọtan to wa nibẹ ni pe awọn igbeyawo ti wọn n ṣe lawọn ile ijọsin ti ko niwe aṣẹ wọnyi ni ko ko lọ nibamu pẹlu ofin igbeyawo, ti wọn ko si le wulo labẹ ofin nigba ti wọn ba nilo ẹ, nitori pe o ti tako ofin igbeyawo ti apa kẹfa, abala kinni in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI