Ẹ SỌ FUN GBAJUGBAJA SỌRỌSỌRỌ NNI, WALE DADA THE GOOD PE E... - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 3, 2019

Ẹ SỌ FUN GBAJUGBAJA SỌRỌSỌRỌ NNI, WALE DADA THE GOOD PE E...


Adeoye Ọlayẹmi, Ekoo

Ko si ibeere meji to n lọ nigboro bayii, bi ko ṣe ti ọkan lara awọn gbajugba sọrọsọrọ ori redio nni, Adewale Dada tawọn eeyan tun n pe ni "The Good" wi pe nibo lo wa lasiko yi, ti ko si tiii sẹni to le dahun ibeere naa.

Fawọn to ba mọ ọkunrin naa daadaa, wọn yoo mọ pe ọrukọ rẹ rinlẹ daadaa ni nnkan bii ọdun mẹrin si mẹta sẹyin sasiko yi, ṣugbọn latigba to ti gba ipo akọwe ijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta ni saa keji ti gomina ana, Ibikunle Amosun ṣe lo ti dabi ẹni pe orukọ rẹ ko fi bẹẹ lu agogo mọ leti awọn araalu.

Bo tilẹ jẹ pe Gbajumọ sọrọsọrọ naa ṣi n ṣe eto lori awọn redio bii Faaji, Sweet, OGBC ati tẹlifiṣan OGTV titi di asiko yi, sibẹ ṣe lo dabi ẹni pe ọkunrin ti ko fi bẹẹ ga pupọ naa, to si fẹran lati maa wọ aṣọ alawọ ewe ati funfun ni gbogbo igba naa ko jẹ aayo fawọn ololufẹ ẹ mọ bayii, eyi ti ko si yẹ ko ri bẹẹ.

Ahesọ kan to ti ẹ ta si wa leti laipẹ yi ni ohun ti wọn n sọ pe oṣelu lo gba iṣẹ naa lọwọ ọkunrin naa, ati pe ogbologbo alatilẹyin Sẹnetọ Ibikunle Amosun ni, ti ko si si nnkan to le gbe e kuro lẹyin ẹ.

Kii Sẹnetọ Ibikunle Amosun too di Gomina ipinlẹ Ogun lọdun 2011, ko sẹni to fẹẹ gbọ sọrọsọrọ min in bi ko ṣe Wale Dada, tawọn eeyan tun mọ si Ọmọ Iya Dada ni Mọkọlọki, latari awọn ọna to maa n gbe iṣẹ naa gba, to si tun tayọ daadaa laarin awọn ẹgbẹ ẹ.

Ko pẹ ti Amosun wọle gẹgẹ bii Gomina ni Wale Dada ti bẹrẹ sii polongo ara rẹ lati di alaga ijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta, to si maa n fi awọn eto ẹ lori redio ati tẹlifiṣan gbe Amosun larugẹ lati wa ojurere rẹ, ko le ba a ri ipo naa gba, ṣugbọn tiyẹn ko woju ẹ rara.

Ṣugbọn ṣe la gbọ pe awọn kan ni wọn ba ọkunrin naa bẹbẹ Amosun nigba to tun gbe apoti ẹlẹẹkeji lati di alaga ijọba ibilẹ, ti wọn si gba lati fun un ni akọwẹ ijọba ibilẹ naa, koun naa le ri jajẹ pada, tori ta a gbọ pe ko fi bẹẹ si owo lọwọ ẹ mọ rara nigba naa.

Bi wọn ṣe sọ pẹ ijọba Amosun ko tẹ awọn araalu, paapaa awọn ara Ado-Odo Ọta lọrun to, lo mu kawọn eeyan kẹyin si Wale Dada to maa n fojuoojumọ gbe Amosun larugẹ, nitori ti wọn lawọn eeyan mọ pe ṣe lo n tan wọn jẹ, eyi ti wọn lawọn eeyan ko fẹ.

Wọn ti ẹ ni Wale Dada gbiyanju lati mu idagbasoke diẹ bawọn agbegbe to ṣoju fun bii ko tun ọna wọn ṣe, bii ko ṣe omi fun wọn, atọn nnkan min in lasiko ẹ, to si jẹ pe lapo ara rẹ pẹluu iranlọwọ awọn kan, ṣugbọn sibẹ wọn ni ṣe lawọn eeyan tun n yinmu sii lẹyin.

A ti ẹ gbọ pe awọn araalu ti Wale Dada ti wa gan an ko fi bẹẹ gba ti ẹ mọ lasiko yi, tori bo ṣe gbaruku ti Ọnọrebu Adekunle Akinlade tẹgbẹ oṣelu APM ti Amosun fa kalẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APM.

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, Wale Dada ṣi wa lori eto ẹ nile-iṣẹ OGTV laarọ yi pẹluu awọn isọngbe e, to si tun ṣeto nile iṣẹ redio Sweet, ṣugbọn sibẹ, wọn lawọn eeyan kii fẹẹ gbọ ọrọ rẹ mọ tori oṣelu to wọ, ti ko si fọlọpọ ṣe e.

Bi irọ ni, bo si jẹ otitọ, a ko ti i le fidi ẹ mulẹ bayii, ohun ti a gbọ ni pe gbogbo ọna ni Wale Dada n wa lati tun wa oju rere Gomina Dapọ Abiọdun to nipo bayii, ko si tun le ri ounjẹ jẹ lasiko yi.

Wale Dada lo gbe awọn bii Gbenga Ogundeyi tawọn eeyan mọ si Fẹlẹfẹlẹ Laye dide nidi iṣẹ orin, bo tilẹ jẹ pe ija ni wọn fi tuka gbẹyin nigba ti adehun wọn fori ṣanpọn, tiyẹn si sa gba iluu Ekoo lọ lọdọ puromota min in to ti n ri owo gidi bayii.

Ṣa o, ohun ti a fẹ jẹ ko ye Ọmọ Iya Dada ni Mọkọlọki bayii ni pe, orukọ rẹ ko rinlẹ, ko si ta mọ bii ti tẹlẹ mọ, to si gbọdọ wa nnkan ṣe sii. Imọnran tawọn kan sọ pe ka ba wọn fun ọkunrin naa ni pe ko ye e ri ara rẹ mọ, ko jẹ kawọn eeyan maa rii, ko si wa gbogbo ọna ti orukọ rẹ yoo fi pada bii ti tẹlẹ, bẹẹ lawa naa n gba a ladura pe orukọ Wale Dada ko nii wọlẹ loju aye rẹ lagbara Ọlọrun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI