EYI NI BI TANKO ṢE DI ADAJỌ AGBA NAIJIRIA - IROYIN AWIKONKO

YÀJÓ-YÀJÓ
Wednesday, July 17, 2019

EYI NI BI TANKO ṢE DI ADAJỌ AGBA NAIJIRIA

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi ni yajo-yajo, ile igbimọ aṣofin agba lorilẹede Naijiria ti bu ọwọ lu iyansipo Onidajọ Tanko Muhammad gẹgẹ bi Adajọ Agba lorilẹede yi

Oni, ti i ṣe Ọjọru, iyẹn Wẹside ni wọn bu ọwọ lu Tanko, lẹyin ayẹwo ti wọn ṣe fun un lọjọ Iṣẹgun ana, ti wọn si daba pe ki wọn yan an sipo naa.

Ṣaaju ni Ajọ to n mojuto eto idajọ ni lorilẹede Naijiria, NJC, rọ Aarẹ Buhari lati sọ Onidajọ Muhammad di Adajọ Agba Naijiria.

Bẹ o ba gbagbe, latigba ti wọn ti yọ adajọ agba tẹlẹ, Onidajọ Walter Ọnnọghẹn lọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu kinni ọdun yi ni wọn ti fi Tanko ṣe adele adajọ agba lorilẹede yi, ko too di pe Aarẹ Muhammadu Buhari fi orukọ rẹ ranṣẹ si awọn aṣofin fun ontẹ lati le mu u kuro ni ipo Adele Adajọ Agba to wa.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI