MERCY AIGBE RỌJO EPE LE AWỌN ỌTA RẸ LORI NITORI DUKIA Ẹ - IROYIN AWIKONKO

YÀJÓ-YÀJÓ
Wednesday, July 17, 2019

MERCY AIGBE RỌJO EPE LE AWỌN ỌTA RẸ LORI NITORI DUKIA Ẹ

Beeyan ba ri gbajumọ oṣerebinrin nni, Mercy Aigbe-Gentry ṣe n gbe awọn eeyan ṣepe nla-nla lori ikanni ayelujara ti Instagram ẹ lana an, wọn yoo mọ pe ko mu ọrọ naa ni kekere rara, paapaa nigba to tun bẹrẹ sii pe ina ẹmi mimọ sọkalẹ sori awọn marimasọ.

Mercy ni ko sẹni to ri oun bayii, pẹluu boun ṣe n ṣiṣẹ karakara kaakiri, toun n ba bi yoo ṣe dara fun igbesi aye oun, ṣugbọn nigba toun ba tun bẹrẹ sii gb awọn aṣeyọri oun jade, wọn tun bẹrẹ sii sọ pe Gomina kan lo ṣe foun.

O sọ pe ina ẹmi mimọ ni yoo sọkalẹ lati jo gbogbo awọn to n sọ isọkusọ nipa ile, mọto, atawọn nnkan toun fi oogun oju oun n ko jọ, nitori pe ko si baba isalẹ kankan to wa nidi aṣeyọri oun.
 

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI