FIJILANTE TAWỌN ADIGUNJALE YINBỌN FUN L'ABẸOKUTA TI JADE LAYE LẸYIN OṢU KAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 30, 2019

FIJILANTE TAWỌN ADIGUNJALE YINBỌN FUN L'ABẸOKUTA TI JADE LAYE LẸYIN OṢU KAN

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, inu ẹdun ọkan bayii ni ọkan lara awọn oṣiṣẹ alaabo ti So Safe Corp nipinlẹ Ogun labẹ ọga wọn Sọji Ganzallo wa bayii, latari bi wọn ṣe padanu ọkan lara awọn oṣiṣẹ wọn, Kẹhin Aigbeṣe dagbere faye lẹyin oṣu kan gbako tawọn adigunjale yinbọn fun un niluu Abẹokuta.

Ṣe lọrọ di bolo o yago lọjọ Mọnde ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹfa ọdun yi ladugbo kan ti wọn n pe ni Ọlọrunṣogo mọ Oke-Lantoro niluu Abẹokuta nigba ti wọn lawọn adigunjale atawọn oṣiṣẹ alaabo So Safe Corps nipinlẹ Ogun doju ija kọ ara wọn.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ni nnkan bi aago mejila aabọ ooru la gbọ pe awọn adigunjale ya wọ adugbo Ọlọrunṣogo mọ Oke-Lantoro, ti wọn si bẹrẹ sii jawọn eeyan lole pẹluu ibọn. A gbọ pe lara awọn kan ti wọn wa ladugbo naa ni wọn ta awọn oṣiṣẹ So Safe yi lolobo, ti wọn si gbera lati lọọ koju wọn.

Wọn ni bawọn adigunjale yi ṣe rii pe awọn oṣiṣẹ So Safe ti wa layika, ni wọn ti ba ẹsẹ wọn sọrọ. Nibi ti wọn lawọn oṣiṣẹ So Safe naa ti n wa wọn lati ri wọn mu la gbọ pe wọn ti mu ọkan lara wọn lati ọwọ ẹyin.

Ibi ti wọn ni oṣiṣẹ So Safe ti wọn pe orukọ ẹ ni Kẹhinde Aigbe, ẹni ọdun mejidinlaadọta ati adigunjale naa ti wọya ija la gbọ pe ọkan lara awọn adigunjale ti ri wọn, ti wọn loo si ṣọ Kẹhinde daadaa, ko too yinbọn fun nikun.

Ọrọ naa di pẹntuka nigba ti wọn lawọn oṣiṣẹ So Safe naa tun yawọ agbegbe naa, ko too di pe gbogbo awọn adigunjale yi na papa bora, loju ẹsẹ ni wọn ti gbe Kẹhinde lọ si ọsibitu FMC to wa nitosi fun itọju.

Wọn ni kani wọn lo iṣẹju marun ki wọn too gbe Kẹhinde de ọsibitu yi ni, o ṣee ṣe ko dakẹ, ati pe ajẹsara ti wọn loo wa lara ẹ ni ko jẹ ko ku soju ogun.

Agbẹnusọ So Safe, Ọgbẹni Mọruf Yusuf lasiko to n gbe iṣẹlẹ naa si AWIKONKO leti sọ pe ara ko nii rokun, bẹẹ ni ara ko nii ro adiẹ mọ bayii laarin awọn atawọn adigunjale nipinlẹ Ogun nitori pe awọn ti tunra mu lati maa koju awọn ọdaran naa lọna igbalode.

Bẹẹ lo gbawọn araalu lamọnran pe ki wọn ma ṣe dẹkun lati maa tete ta ileeṣẹ awọn lolobo nitori pe eto aabo ipinlẹ Ogun lo jẹ ẹgbẹ wọn logun.

Bakan naa lo tun jẹ ko ye wa pe awọn ti ṣe ojuṣe awọn lori iku Kẹhinde, nitori pe adanu nla lo jẹ fawọn to si gbadura pe Aṣẹda yoo bu ororo itura sawọn mọlẹbi oloogbe naa lọkan

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI